WASIU AYINDE F’ESI F’AWỌN TO N PE KO L’ẸTỌ ATI JẸ AWUJALẸ IJẸBU ODE

Gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde Marshall ti awọn miiran n pe ni Kwam 1 n lo ti fi orin s’ọrọ gba awọn to n ni ko wa ṣalaye bi oye Awujalẹ ìyẹn ọba ilu Ijẹbu-Ose ṣe tọ si lati jẹ.

Bi aṣa awọn olorin lati ma lo agbo ere wọn lati f’esi si ọrọ to n lọ l’aarin ilu abi nipa wọn, Oluaye Fuji naa fi orin ki ẹnu bọ ọrọ. Eyi lo si n tẹlẹ bi ero rẹ lati jẹ Awujalẹ Ijẹbu-Ode ṣe le’de ninu lẹta kan to lu ja’ye amọ ti ariwo n wa lati awọn aaye kan pe Wasiu Ayinde Oluaye Fuji kọ lo kan.

Eyi lo fa esi ti Wasiu Ayinde f’orin kọ. Ninu agbada olowo nla alawọ bulu-funfun (skye-blue) ti Kwam 1 wọ l’oju agbo naa lo ti fọ esi pe “mo letọ lati jẹ Awujalẹ, awọn to ba ru l’oju, ipade di popo… Ki eniyan o to jẹ oye Ọtunba Fidipọte ati Olori Ọmọ-Ọba Akilẹ Ijẹbu-Ode, o ni lati jẹ ọmọ-ọba daju. Ẹ jẹ ki n ṣẹ ẹnu ku, ipade di oju ogbagadi, ṣugbọn ẹtọ mi jẹ Awujalẹ”

Wọnyi ni itumọ awọn oun ti Ọba Fuji to n fẹ lati di ọba Awujalẹ Ijẹbu-Ode fi orin kọ. Ni bayii ọpọ lo tun wo oye ibi ti ọrọ naa ma ja si, ṣugbọn ṣa ti awọn iwoye naa ṣe ọtọtọ. Awọn kan gbagbọ pe ibaṣepọ Kwam 1 ati Aarẹ Bọla Tinubu ati Gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun ni Wasiu Ayinde gb’ọkan le.

 Awọn miran si gbagbọ pe ojulowo ọmọ-ọba Ijẹbu-Ode ni to lẹtọ si ipo naa bi awọn ti ẹ n pe ile wọn kọ lo kan bayii. Bẹẹ la tun ri awọn to n pe ilesanmi dun ju oye lọ fun Wasiu Ayinde pe Ọba Fuji to jẹ ti to ati pe bi yoo ti ẹ jẹ ọba asiko ko ti to t’ori awọn ṣi fẹ gbadun rẹ diẹ si gẹgẹ bi olorin ti iru rẹ s’ọwọn.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search