Gẹgẹ bi ọkan pataki ninu awọn perete to jẹ gbajumọ ṣugbọn ti ọpọ mọ wọn fun dida ọwẹkẹ (chitchat) l’ori ayelujara, Don Jazzy ni ọmọbinrin @itohan_olat kan ṣa dede fa (tag) si’nu atẹs’aye (post) kan l’ori ikanni X (Tweeter) to fi n beere fun ẹbun kekere fun ọdun Keresimesi lọwọ Don Jazzy ti awọn miran a ma pe ni Don Baba.
Atẹs’aye (post) naa lọ bayii pe “Yi o wu mi ki @DonJazzy o kan beere ohun ti mo fẹ fun ọdun Keresimesi. Mo ṣe ileri lati ma ṣe iṣe wọbia.”
Gẹgẹ bii iṣe Don Jazzy lati kan ṣadede ma takurọsọ pẹlu ẹnikẹni l’ori ayelujara, lo fi esi si atẹs’aye (post) ọmọbirin naa pe “Ẹrin pa mi! Oya ki l’ohun to o fẹ? Nitori mo fẹran ọrọ ajuwe (bio) rẹ, mo si tun kẹfin pe o ti ma n da si awọn atẹs’aye mi l’ati ẹyin wa. Mo dupẹ.”
Esi ti ọmọbinrin naa yoo fọ, lo ba ni “Jesu o se. Mo jẹ awọn gbese kan ti mo fẹ san ki ọdun to pari. Ṣugbọn, pataki julọ mo fẹ bẹrẹ ajọ ẹlẹyinju aanu “Mercy Foundation” lati ma ṣe iranwọ owo fun itọju awọn alaisan kidirin (kidney dialysis) l’ọsọsẹ nitori aburo ohun ọkunrin ku nipasẹ ailera naa”.
Ni Don Jazzy ba ke gbajare pe “Haa Anti, ibeere yin yi da bi inawo titi lai ninu apo alapo. Ẹ o si ṣ’aanu ọmọkunrin (Don Jazzy) yii.”
Bi awọn onwoye l’ori ayelujara ṣe gbọ pẹkẹ itakurọsọ yii ni wọn ti ta mọ’ra pẹlu iwoye ọtọtọ. Awọn kan ni ọkanjua ni ọmọbinrin naa bẹẹ awọn miran ni ẹnu ẹni laa fi n pe temidire.