Lẹyin ti Aanu iyẹn ọmọ ti Ayọ Labinjoh ni oun bi fun Davido beere pe ki Davido o wa ṣe ayẹwo DNA lati f’ẹnu ọrọ jo’na l’ori awuyewuye pe boya Davido ni baba ọmọ naa abi bẹẹ kọ.
Lẹyin ti Aanu iyẹn ọmọ ti Ayọ Labinjoh ni oun bi fun Davido beere pe ki Davido o wa ṣe ayẹwo DNA lati f’ẹnu ọrọ jo’na l’ori awuyewuye pe boya Davido ni baba ọmọ naa abi bẹẹ kọ. Amọ ṣa, Davido iyẹn gbajugbaja irawọ olorin to tun jẹ ọmọ baba olowo ti pe Aanu kii ṣe ọmọ oun, ti awọn ayẹwo DNA lat’ẹyin wa sí ti fì’dí rẹ mu’lẹ pe oun kọ ni baba ọmọ naa yatọ fun oun ti Ayọ Labinjoh to jẹ iya ọmọ n wi.
Ọrọ yii ti wa fọ’ju pọ pata bayii, ti ọrọ naa si ti wa l’ori ete ọpọ l’ori ayelujara ati l’aarin ilu. Davido ati awọn eniyan rẹ ni ayẹwo DNA marun-un lo ti waye, ti Ayọ Labinjoh si pe igba kan ṣoṣo ni ayẹwo DNA naa wa’ye ti Oloye Deji Adeleke to je baba Davido, ti Ayọ Labinjoh si tun juwe rẹ gẹgẹ bíi awuruju.
Diẹ l’ara awọn to ti dasi ni Kẹmi Olunlọyọ to wa ni iha Aanu ati iya re, bẹẹ latun ri Oye Myke ti oun naa parọwa si Davido lati gbiyanju ṣe ayẹwo DNA tuntun l’ojuna ati le dẹkun awuyewuye to n lọ l’ọwọ. Ko tan si’bẹ, Daddy Freeze naa ko gbẹyin, to n si faramọ iha ti Davido l’ori ọrọ yii.
Titi di akoko yii, ọrọ naa ko ti yanju ṣugbọn ti arọwa ṣi n lọ pe ki Davido o mu ẹnu aye kuro, ko si gba lati ṣe ayẹwo DNA ti ko ni ẹja n bakan rara. Bẹẹ awọn miran tun pe ẹkọ nla ni f’awọn obinrin lati ṣọra ki wọn o ma ko s’ọwọ alagbeda.