OBINRIN MẸTA ỌTỌTỌ NI MO N FẸ PAPỌ – NE-YO

Gbajugbaja onkorin takasufe kan, to tun ti tẹwọ gba ami ẹyẹ Grammy ti orukọ rẹ n jẹ Ne-Yo lo ti kede f'aye pe obinrin mẹta l'oun n fẹ papọ ṣugbọn ti awọn ko gbọdọ fẹ ẹlomiran.

Ne-Yo ẹni ọdun mẹrindilaadọta (46) lo sọ eyi mọ ọrọ l’asiko to n kopa l’ori eto kan ti wọn pe ni Sherrie, ni’bẹ lo ti sọ di mimọ pe obinrin mẹta iyẹn Arielle Hill, Cristina ati Moneii ni oun fẹ papọ pẹlu imọsi gbogbo wọn ṣugbọn ti awọn ko le fẹ ẹnikẹni.

O ṣalaye pe l’ẹyin ti igbeyawo oun ati aya rẹ tẹlẹ Crystal Renay ti tuka l’atari ẹsun pe oun bi’mọ si’ta leyi to fa ipinu oun lati ma pa irọ fun obinrin kankan mọ. O ṣalaye pe oun pe ọrẹbinrin oun, ti oun si fi da l’oju pe oun fẹran rẹ gidi gan-an ṣugbọn ti oun yoo tun fẹ lati fẹ awọn obinrin miran pẹlu rẹ.

Ko tan sibẹ, Ne-Yo ni l’ẹyin ti awọn obinrin naa f’ara mọ fifẹ ọkunrin kan ṣoṣo l’ẹẹkan ṣoṣo lai ni ọkunrin miran ni oun naa ti pinu lati maa ṣiṣẹ karakara lati lee tẹ gbogbo wọn l’ọrun ni asiko ajumọṣe ati igba ọtọtọ

Awọn eniyan ti wa n kọ ha l’ori iru ifẹ Ne-Yo yii ti awọn kan si ni kinni naa daa gba.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search