Pasitọ iyẹn Oluṣọ Aguntan ile ijọsin kan l’eko, David Christian Centre ti orukọ rẹ n jẹ Pasitọ Kingsley Okonkwo lo mọ ṣe ohun meeriri kan t’aye ti n pa’riwo bayii, n ṣe pasitọ naa ya tatuu (tattoo) s’ọwọ, l’eyi to ti fa awuyewuye l’oju awọn eniyan paapaa julọ awọn ẹlẹsin igbagbọ l’ori boya irufẹ ohun naa tọ’na.
Ṣebi ẹsẹ bibeli kan to gbajumọ daadaa, iyẹn iwe Johanu, ori kẹta, ẹsẹ kinni (John 3:16) ni pasitọ naa ya si abala ọwọ rẹ t’ọrọ fi d’ariwo.
Ohun to wa jẹ ki ọrọ yii o l’agbara pupọ, ko si ka ọpọ l’ara ni pe, pasitọ yii wa ninu awọn ojiṣẹ Ọlọrun to gbajumọ l’ori ayelujara, to si tun l’ero l’ẹyin daadaa.
Ẹwẹ, pasitọ yii fun’ra rẹ ti wa ja’de lati jẹ ko di mimọ pe ẹsin Kristẹni ko fi ibi kankan kọ yiya tatuu sara, ti eyi si n wa’ye tẹle bi fọnran tatuu naa ṣe ti da ariyanjiyan si’lẹ ni’gboro. Bẹẹ lo gba wọn niyanju lati maa le’pa idagbasoke ninu ẹmi, iwa, ati ipa rere dipo fífi ọkan si oun t’ara nikan.
L’ara awọn to ni ko si laifi ninu iwa pasitọ yii lati ri Mike Abdul to jẹ gbajumọ olorin ẹmi ati pasitọ miran Abel Damina ti wọn gba pe ko si oun to buru ni’bẹ rara, ṣugbọn ti awọn kan kọ ja’lẹ pe ki i ṣe oun itẹwọgba ninu ẹsin Kristẹni.