Mo Duro K’owo De Kin To D’ẹnu Kọ Iyawo Mi – Dapson

Mo Duro K’owo De Kin To D’ẹnu Kọ Iyawo Mi – Dapson

Ọkunrin kan to jẹ adari fọnran orin (Music Video Director) ti orukọ rẹ n jẹ Fẹmi Dapson ṣugbọn ti ọpọ mọ si Director Dapson lo ti fi oju-iwoye rẹ han ni’pa ipa ti ko ṣe ko danu ti owo n ko l’ori ọrọ ifẹ.

Gẹgẹ bi Dapson ṣe m’ẹnuba ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ti ko’pa laipẹ yii, pẹlu aya rẹ, Simi Sanya. Dapson jẹ ko di mimọ pe oun ko le da ẹnu ifẹ kọ aya oun ni’gba naa lat’ari aisi owo l’ọwọ. Ti oun si nilo lati duro de igba ẹẹkeji ti oun ṣ’alaba pa’de rẹ l’asiko yii ni’lu Akurẹ ti owo si ti n d’ọwọ ki oun to le d’ẹnu ifẹ kọ.

Siwaju si, Dapson ṣ’aleye pe “mo mọ ipa pataki ti owo nini ko ninu ọrọ ifẹ ni ko jẹ kin d’ẹnu ifẹ kọ Simi titi di igba ti owo de.” Ko tan si’bẹ, Dapson tun jẹ ko di mimọ pe oun kundun tita abo l’ọrẹ.
Ọrọ Dapson l’ori ayelujara ti wa bi oniruuru iwoye. Awọn kan gbagbọ pe irufẹ ipinu Dapson ko sunwọn rara, bẹẹ ni awọn kan gbagbọ pe ootọ ọrọ ponbele ni Dapson sọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search