Gbajumọ kan l’aarin ilu ti orukọ rẹ n jẹ Tokẹ Makinwa lo ti ṣ’alaye idi ti ko fi san ọrẹ idamẹwa mọ ni ile ijọsin. Ni iwoye Tokẹ, o tọka si pe oun ti dagbasoke si, ti oun si tun ti lekun l’oye, to fa bi oun ṣe mọ pe idamẹwa sisan da bi igba ti eniyan ba fi ṣibi bu omi si okun.
L’asiko ti Tokẹ n ṣe arojinlẹ l’ori iriri rẹ nipa ẹsin ati ọrọ ẹmi lo jẹ ko di mimọ pe, ẹsin le ṣe akoba fun ni nigba miran paapaa julọ nipasẹ iwa awọn ijọ ati adari ijọ.
Iwoye Tookẹ ni pe ọgọrọ ọlọrọ ni ijọ ti pese ṣugbọn ti ọkẹ aimọye awọn ọmọ ijọ miran n si n tiraka lati jẹ, ti o si san lati ṣe fun awọn alaini taara dipo kiko owo wa sinu ijọ gẹgẹ bi idamẹwa.
“Mo kan n da ro pe, ti mo ba ni owo dani, ti ẹnikan si nilo owo ile, kilode ti n lọ ko fun ile (ijọsin) kan?” Tokẹ ṣalaye pe, iwoye oun l’ọwọ yii ni lati fi owo ran awọn to nilo rẹ ni tootọ bi ile iwosan, ile igbẹbi ati eniyan ti oun mọ pe o nilo iranlọwọ lootọ.
Siwaju si, Tokẹ sọ itan kan nipa ara rẹ, pẹlu bo ṣe fi odidi owo to gba fun ipolowo ile-iṣẹ kan jin fun ile ijọsin ṣugbọn ti oun ko le ṣe bẹẹ mọ nitori ti oun ri ọpọ ile ijọsin gẹgẹ bii ibi ti wọn ti jẹun yo.