Awọn ohun ti Ọlaṣubomi Raheem Ọkọya to jẹ ọmọ bibi inu baba olowo Eko kan, Rasaq Ọkọya ti ọpọ mọ si Eleganza tọka si f’aye gẹgẹ bi awọn oun to nifẹ si ati eyi to korira lo ya ni l’ẹnu l’ọpọ.
Ninu ifọrọwanilenuwo to ṣe laipẹ yii pẹlu ile-iṣẹ iroyin BBC Yoruba ni Raheem, ọdọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun (22) to jẹ oniṣowo ati olorin, ti sọ oriṣiriṣi nipa ara rẹ ati awọn iriri to ti ni.
O jẹ ko di mimọ pe oun korira iroyin ofege “Awọn agberoyin jade kudun ati ba mi jẹ l’oju araye, Ṣubomi l’ọtun, Ṣubomi l’osi, wọn a ma yi ọrọ mọ mi l’ọwọ, ti wọn a si sọ ọrọ kekere di babara nitori wọn mọ pe iroyin buruku a ma ta. Botilẹjẹ pe a ko ri ọgbọn da si iroyin gbigbe jade nibi ti aye laju de ṣugbọn o ma n dun mi jọjọ bi wọn ba n fi iroyin sọ mi lẹnu, ti eyi si mu ki n korira iroyin ofege.” Siwaju si, Raheem tun jẹ ko di mimọ pe botilẹjẹ pe ọjọ ori oun kere jọjọ ti oun fi de ipo ọga agba ile-iṣẹ Eleganza ti baba rẹ da silẹ ṣugbọn ti eyi ko ba ọfẹ de nitori ti oun ṣiṣẹ de’bẹ ni lati nnkan ọdun mẹwaa sẹyìn to ti n f’oju si’ṣẹ l’abẹ baba rẹ.
Ko tan si’bẹ, Raheem tun mẹnuba awọn ohun to ni’fẹ si, “mo fẹran owo l’ọpọ l’ọpọ… awọn orin ti mo gbọ da’gba ti jẹ kin ti kekere ni’fẹ si orin, kin to wa di olorin gan-an fun’ra mi. Iriri aye ti mo ni ni mo n sọ di orin. Mo fẹran Wasiu Ayinde (Oluaye Fuji), lati kekere ni mo ti n gbọ wọn. Awọn eniyan gbagbọ ninu iṣẹ orin mi ti wọn si n d’okowo si’nu rẹ.”
Lakotan, Raheem jẹ ko di mimọ f’araye pe baba rẹ iyẹn Baba Eleganza ni alawokọṣe (model) oun akọkọ, ti oun si l’ero pe oun yoo mu ori baba naa wu l’ọjọ kan. Bẹẹ lo tun dupẹ l’ọwọ mama rẹ to pe ni ‘Mummy of Lagos” iyẹn Oloye’binrin Ṣade Ọkọya. Raheem dupẹ f’awọn obi mejeeji nitori ti wọn ri ọmọ rere wo si oun l’ara.