UZOR ARUKWE ṢE’LERI ẸWỌN F’ẸNI TO L’OUN FUN BAMBAM, OṢERE AKẸGBẸ RẸ L’OYUN

Wahala nla lo n l’ọwọ bayii l’ori bi bulọga kan l’ori ayelujara ṣe f’ẹsun kan gbajugbaja oṣere Nollywood nni, Uzor Arukwe pe o fun oṣere akẹgbẹ rẹ iyẹn Bamikẹ Ọlawunmi ti ọpọ mọ si BamBam l’oyun, ti eyi si ti mu ki ile BamBam o daru, l’ẹyin ti ọkọ rẹ Teddy A ni oun ko ṣe mọ.

Awuyewuye ẹsun kanjan yii lo mu ki Uzor Arukwe o jade l’ori ikanni Instagram pe ẹnikan ti oun ko ni darukọ ko ma ba di ipolowo ọfẹ lo n fi ẹwọn run imu. Ti tọun yoo si gb’oorun ara rẹ laipẹ.

Ẹwẹ, ẹ ranti pe Uzor ati Bambam lo jọ ko’pa gẹgẹ bii ololufẹ ninu sinima olokiki kan l’ọdun to kọja to si mu ki awọn eniyan ma pe ifẹ wọn ninu ere ni ootọ l’oju aye. Bẹẹ lo jẹ pe l’ẹnu l’ọwọ-l’ọwọ yii la kẹfin awọn mejeeji ninu baalu kanaa lati jọ lọ si ibi ode ariya kan bẹẹ ni akiyesi tun wa pe nnkan ko toro l’aarin ọkọ-ile BamBam ati Teddy A l’atari pe awọn mejeeji ti d’ẹyin l’ẹyin (unfollow)ara wọn l’ori ikanni Instagram.

Amọ ṣa, Uzor ni ko mu ẹsun naa ni kekere, to si ti ṣeleri ẹwọn fun ẹni to fi irufẹ ẹsun naa kan-an. Uzor pe “ẹ gbagbọ pe, a o f’ẹni naa j’ofin. Imu ẹran iya la o mu oni tọun.” Ẹwẹ, BamBam ati ọkọ rẹ ni ko ti fọ gbolohun lati tako abi fi’di awuyewuye naa mu’lẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search