Ayefẹlẹ ati BBO Ji Mi L’orin Kọ – Beautiful Nubia

Gbajugbaja olorin ọgbọn ati imisi, Ṣẹgun Akinlolu ti ọpọ mọ pẹlu orukọ elere rẹ, iyẹn Beautiful Nubia lo ti ja’de fẹsun kan gbajugbaja onkọrin ẹmi nilana Tungba, Omọwe Yinka Ayefẹlẹ ati irawọ tuntun l’agbo orin ẹmi, Arakunrin Bakare Boluwatifẹ Oluwatobi ti ọpọ mọ si BBO pe wọn ji oun l’orin kọ.

Ninu atẹjade kan ti Beautiful Nubia gbe ja’de l’oju opo ikanni Instagram lo ti tọka si pe orin “My Faith in God (Igbagbọ Ireti) ti Ayefẹlẹ gbe ja’de l’ọdun 2012, to fi mọ orin “Amin” to ja’de ninu ọdun 2026 yii lat’ọwọ BBO lo jẹ ajiwo abi ajikọ orin oun kan ti akọle rẹ n jẹ “Seven Lives.”

Siwaju si, Beautiful Nubia f’ẹsun kan awọn mejeeji pe bi orin oun “Seven Lives” ti dun l’eti ni Ayefẹlẹ ati BBO ṣe adakọ rẹ l’ọna ti wọn lai gba iyọnda l’ọwọ oun. Nubia wa beere pe “igba wo gan-an ni awọn ọmọ Naija paapaa julọ awọn ti wọn pe ni olorin ẹmi yoo bẹrẹ si ni b’ọwọ fun ẹtọ iṣẹ ọpọlọ (copyright)?”

Ọrọ yii lo da igboro ru bayii l’atari bi ọpọ ṣe mọ Beautiful Nubia gẹgẹ bii olorin to da yatọ ti ko si ni awuyewuye kankan l’ori, ti wọn si n pe bi aja Beautiful Nubia ko ba ri ko ni gbo. Ẹwẹ, BBO ati Ayefẹlẹ ni ko ti fọ esi kankan l’ori ọrọ yii.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search