Iya Jẹ Papaya Ex L’ọwọ Ọlọpa Eko

Irawọ ori ikanni TikTok kan ti ọpọ mọ si Papaya Ex lo ke gbajare pe awọn kan ninu ẹṣọ ile-iṣẹ ọlọpa ipinlẹ Eko lo fi ọwọ ba oun, ti wọn si tun ṣe oun baṣu-baṣu.

Ninu fọnran ti ọmọbinrin naa gbe ja’de lo ti fi ẹsun kan pe awọn ọlọpa kan da oun duro ni igboro Eko l’asiko ti oun wa ọkọ kọja ni oru, ti wọn si fi idi ibọn gba oun l’oju, ti wọn si tun f’ọwọ tẹ igba-aya oun.
Ọrọ yii ti Papaya fi l’ede l’ori fọnran yajoyajo (live video) to n ṣe lo mu ki awọn eniyan paapaa julọ awọn ololufẹ rẹ gba’rata fun-un.

Ẹwẹ, agbẹnusọ ọlọpa ni ipinlẹ Eko, DSP Benjamin Hundeyin naa l’orukọ ile-iṣẹ ọlọpa tọ’ka si pe irawọ ori ikanni TikTok lo kọja aaye ara rẹ l’atari bo ṣe kọ lati fi ara rẹ han awọn ọlọpa, to si tun kọ lati jẹ ki wọn o yẹ ọkọ rẹ wo. Hundeyin ni igbe “ṣẹ ma sọ pe ẹ o mọ mi, awọn ọga yin gan-an o le pe awọn ko mọ mi” ni Papaya pa titi ti wọn fi ni ko niṣo ni agọ ọlọpa pẹlu ọkọ ati awọn marun-un to wa ninu rẹ, ọkunrin mẹta ati obinrin meji, ti ọkọ awọn ọlọpa si tẹle.

Ko tan si’bẹ, alukoro ọlọpa Eko tun ṣalaye pe n ṣe ni Papaya ni ki wọn wa ọkọ wọn s’are kuro, ki wọn o le yọ bọrọ l’ọwọ ọkọ ọlọpa to n tọ wọn l’ẹyin lọ si agọ ọlọpa.

Ọrọ yii ko ti sunmọ ibi ati yanju pẹlu bi awọn Papaya ti n ṣẹ, ti ikamudu awọn ọlọpa naa n ṣẹ l’ori ọrọ yii. Awọn eniyan l’ori ayelujara ti n fi iwoye ọtọtọ wọn l’ede l’ori iṣẹlẹ yii botilẹjẹ pe ọrọ to ti yanju.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search