Irawọ agbabọọlu ọmọ orilẹ-ede Naijiria to n gba bọọlu jẹun ni ilẹ Gẹẹsi gẹgẹ bi atamatase l’ọwọ iwaju fun ikọ Wolves. Tolu Arokodare naa ti wa ninu awọn agbabọọlu ni ilẹ gẹẹsi to n f’oju wi’na idẹyẹsi ẹlẹyamẹya (racism) lat’ari bi awọn kan ti n f’ẹnu ṣata rẹ l’ori ikanni Instagram l’ọjọ Aiku Sunday anaa l’ẹyin ti ikọ rẹ padanu ami ayo kan s’odo s’ọwọ ikọ Crystal Palace.
Ẹwẹ iṣẹlẹ yii ko mọ l’ori Tolu nikan, o ṣẹlẹ si agbabọọlu l’ọwọ ẹgbẹ nini ikọ Sunderland, Romaine Mundle, bẹẹ ṣaaju ni Hannibal Mejbri to n gba l’ọwọ aringbungbun fun ikọ Burnley ati adiẹyinmu ninu ikọ Chelsea, Wesley Fofana naa f’ara k’aṣa Idẹyẹsi buruku yii.
Ikọ Wolves ati agbabọọlu Tolu bi awọn to ku to la iru eyi kọja ti bu ẹnu atẹ lu irufẹ iriri buruku yii gẹgẹ bii ohun ti ko b’oju mu rara. Tolu pe “ohun iyalẹnu nla ni pe awọn eniyan le s’ọrọ ẹlẹyamẹya, ki wọn o si mu jẹ gbe.”
Ẹwẹ, ajọ “Kick It Out” to ma n gbogun ti iwa ẹlẹyamẹya jẹ ko di mimọ ni irọlẹ ọjọ Aiku Sunday pe: “Opin ọsẹ yii ko sunwọn rara l’ori ayelujara, agbabọọlu mẹrin ọtọtọ lo koju Idẹyẹsi ẹlẹyamẹya ṣugbọn a mọ pe a ma a wa’ye l’ọpọ igba yatọ fun eyi. O yẹ ki wọn o le f’oju awọn oniwa laabi naa han fun ijiya to yẹ.”