Ọga agba ile-iṣẹ iwe iroyin alariya, Ovation Magazine to tun ti fi igbakan ri gbero lati jẹ aarẹ l’orilẹ-ede Naijiria, to si jẹ oloye ninu ẹgbẹ oṣelu ADC l’ọwọ yii, Dele Momodu lo ti kọminu l’ori iṣọwọ ti awọn gomina kọọkan nilẹ yii fi n ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bọla Tinubu.
L’asiko ti Momodu n kopa l’ori eto kan ni ile-iṣẹ amohunmaworan aladani kan nilẹ yii lo ti ṣe ikilọ pe ewu nla n bẹ bi Bọla Tinubu ba le wọ’le si’po aarẹ lẹẹkeji ni ọdun. O jẹ ko di mimọ pe aṣẹ ijọba orilẹ-ede le di ti abaṣẹwaa labẹ idari Tinubu.
Ko tan si’bẹ, Momodu tun koro oju si bi ọpọ awọn gomina ṣe n darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC paapaa julọ pẹlu bi Gomina Ahmadu Fintinri ti ipinlẹ Adamawa naa tun darapọ ni tuntun.
Momodu ṣalaye pe “awọn gomina wa n ja fita-fita lati ri pe Tinubu wọ’le ẹlẹẹkeji, wọn fẹ le sọ ara wọn di janduku rẹ… Bi ẹnikan ṣoṣo ba le gbakoso gbogbo ilu bi Tinubu ṣe ti ṣe ni saa akọkọ yii, bi iru ẹni bẹẹ ba wo’lẹ ẹẹkeji, n ṣe ni yoo ko gbogbo ilu ni papa mọ’ra lati ma jẹ gaba le wọn l’ori gẹgẹ bii olori abaṣẹwaa (dictator). Eyi l’ewu jọjọ f’awọn gomina nitori ẹru Tinubu ni awọn gan-an yoo da nigba yẹn.
Ni’pari, Dele Momodu rọ awọn ara ilu lati ya oju l’alakan fi n ṣọ’ri, ki wọn o si ma gba fun ẹnikẹni lati ni agbara kọja bo ti yẹ, ki irufẹ agbara apọju bẹẹ o ma ba fi ilu sabẹ igbekun.