Itafaaji

Eyi laṣiiri iku ojiji to pa Adukẹ Gold, akọrin ẹmi!

Titi dasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ ni ojo ọrọ ibanikẹdun ati idaro ṣi n rọ wọle lori ẹrọ ayelujara, latari bawọn oṣere tiata ilẹ wa, awọn Ojiṣẹ Ọlọrun, atawọn ololufẹ gbajumọ akọrin ẹmi ilẹ wa nni, Adukẹ Ajayi, tawọn eeyan mọ si Adukẹ Gold, ṣe jade laye lojiji, lẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34) pere.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kejila, ọdun 2024 ta a wa yii ni ọkan lara awọn akọrin ẹmi ẹlẹgbẹ rẹ toun naa gbajumọ bii iṣana ẹlẹta, Abilekọ Esther Igbẹkẹle, kede loju opo Instagiraamu rẹ pe: “Sun-un’re o, Adukẹ Gold. Ọgagun kan tun ti lọ.”

ITAFAAJI fidi rẹ mulẹ pe ọsibitu fasiti Ibadan, iyẹn University College Hospital, UCH, lobinrin naa mi eemi ikẹyin si lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Kẹjọ ọdun yii.

Awuyewuye to kọkọ gbode lẹyin iku obinrin adumaadan naa ni pe lasiko ti wọn n ṣiṣẹ abẹ lati latari arun iju, tawọn eleebo n pe ni faiburọọdu (Fibroids) kuro lara rẹ ni kinni naa gbodi, to si ṣe bẹẹ ta teru nipaa. Ninu fidio kan to kọkọ ja ranyin lori ẹrọ ayelujara, wọn ni niṣe l’Oloogbe naa n pariwo, to n jẹrora gidi, to si n lọgun, ko too di pe okun tan ninu rẹ, to si dakẹ.

Amọ awọn alaṣẹ ileewosan UCH ti ni ọrọ naa ko ri bawọn eeyan ṣe n sọ ọ rara. Alukoro ileewosan ọhun, Abilekọ Funmilayọ Adetuyibi sọ fawọn oniroyin kan pe loootọ UCH ni Adukẹ Gold dakẹ si, o ni nnkan to fẹẹ fa idarudapọ lẹyin iku akọrin ẹmi, tawọn kan tun mọ si Adukẹ Pẹnkẹlẹ yii ni pe awọn ko tete kọ iwe-ẹri iku rẹ, ki wọn le yọnda oku rẹ fawọn mọlẹbi, ati pe ohun to fa eyi ni pe ki i ṣe ọdọ awọn dokita to n tọju rẹ latigba to ti de sileewosan ọhun lo dakẹ si, o ni wọọdu gbogbogboo lo ti n gba itọju latilẹwa, amọ ẹka kan ti wọn ti lọọ ṣe ayẹwo ijinlẹ kan sara rẹ, ti wọn n pe ni diagnosis ni iku ka a mọ, tori naa, awọn ni lati duro de dokita to ti n ṣetọju rẹ latẹyinwa, lati kọ sabukeeti iku naa, gẹgẹ bii ilana aa-tẹle ileewosan UCH.

Alukoro naa fi kun un pe ki i ṣe gbogbo hulẹhulẹ ohun to ṣẹlẹ loun le maa ka boroboro lori afẹfẹ, amọ gbogbo itọju to yẹ lobinrin ọhun ri gba latigba ti wọn ti gbe e wa lati ọsibitu ẹkọṣẹ iṣegun fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ, niluu Agọ-Iwoye to wa tẹlẹ lọjọ kẹta oṣu Kẹjọ yii, ko si sẹni to fura pe nnkan le pada yiwọ lagọọ ara rẹ, amọ ọrọ iku kọja bẹẹ.

Bakan naa ni ọkan lara mọlẹbi Oloogbe, Pasitọ Ajayi Aderọgbọ, to jẹ ẹgbọn akọrin ẹmi naa tan imọlẹ si iku rẹ, o ni ki i ṣe arun faiburọọdi lo pa Adukẹ Gold, bẹẹ ni ko ku lasiko iṣẹ abẹ rara. Pasitọ Ajayi ni “ẹnikẹni to ba n gbe iroyin irọ yii kiri gbọdọ jawọ o, ọmọbinrin ṣaisan, o ni arun jẹjẹrẹ abẹnu, a si gbe e lọ ileewosan UCH Ibadan, amọ o ṣeni laaanu pe o ku sibẹ. Ọpẹ ni f’Ọlọrun pe o ti lọọ sinmi lọjọ Aje, ọjọ kejila oṣu Ọgọọsi. Ohunkohun to ba tun yatọ si eyi, irọ patapata ni.

Yatọ si Esther Igbẹkẹle, lara awọn Ojiṣẹ Oluwa to ṣedaro Oloogbe yii ni Wolii Sam Olu-Alọ ti ijọ Christ Apostolic Church (CAC)  Adamimogo Grace of Mercy Prayer Mountain Worldwide, o ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii irawọ to n tan yinrin-yinrin lagbo awọn onkọrin ẹmi ilẹ wa, o si sọ pe orin rẹ ti bu kun ọgọọrọ idile pẹlu awọn ọrọ iwaasu to kun inu rẹ.

Lara awọn to ṣedaro lẹyin Oloogbe ni onitiata Yọmi Fabiyi, Jaiyeọla Kuti, Tawa Ajiṣefinni, Samuel Ajirebi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search