Itafaaji

Eyi laṣiiri to wa laaarin emi ati Onyeka Onwenu to ku – Sunny Ade

Yoruba bọ wọn lọjọ iku laa dere, gbaju-gbaja onkọrin Juju nni, Sunday Iṣọla Adegẹye ti gbogbo eeyan mọ si King Sunny Ade, ti sọrọ lori ajọṣepọ to wa laarin oun ati ilumọ-ọn-ka olorin afẹ elede oyinbo ati ti Ibo nni, Abilekọ Onyeka Onwenu, to d’oloogbe l’ọsẹ to lọ lọhun-un.

Ṣe tipẹtipẹ sẹyin l’awuyewuye ti wa lori ajọṣe awọn eekan olorin mejeeji yii, paapaa lasiko kan l’ọdun 1989, nigba t’awọn mejeeji jọọ kọrin ninu awo orin kan ti wọn pe akọle rẹ ni ‘Wait for Me,’ to tumọ si (Duro de Mi) lede Yoruba.

Orin ifẹ l’orin ọhun, awọn ọrọ ifẹ ati ijo jẹlẹnkẹ tawọn ololufẹ nifẹẹ si, eyi tawọn mejeeji jo ninu awo naa mu ki ọpọ bẹrẹ si i gbe e pooyi ẹnu pe afaimọ ni Sunny Ade ati Onwenu ko ti maa ṣe wọle-wọde lọkọ-laya, wọn ni ajọṣe wọn ju ti okoowo kikọrin papọ lọ, awọn mejeeji ti n ṣe kurukẹrẹ akọ atabo ni.

Amọ nigba naa lọhun-un, Sunny Ade ko fesi kan, bẹẹ ni Onyeka Onwenu ko gbin lori awuyewuye naa, titi ti ina ọrọ ọhun fi rọlẹ.

L’ọsẹ to kọja yii, nigba ti Ọba orin Juju afi-gita-dara yii, King Sunny Ade, ṣabẹwo ibanikẹdun sawọn mọlẹbi Oloogbe Onyeka Onwenu to jade laye l’ọgbọnjọ oṣu Keje, ọdun 2024 yii ni KSA ṣiṣọ loju eegun ajọṣe oun ati arẹwa obinrin agbalagba naa.

Sunny Ade ni idi toun ko ṣe le sọ pato boya awọn n fẹra nigba naa lọhun-un ni pe, loootọ loun dẹnu ifẹ kọ Onyeka o, amọ ko fun oun lesi kan san-an, ko sọ foun pe oun gba, bẹẹ ni ko sọ poun o gba.

O ni: “Mi o mọ bi mo ṣe fẹẹ ṣalaye ẹ, ṣe ẹ mọ teeyan ba gbọ nipa iku ẹni to nifẹẹ gidi, to jẹ pe ọrọ ẹni naa kan igbesi-aye ati iṣẹ eeyan, o maa n ri bakan.

“Orin ‘Wait for Me’ ta a jọ kọ yẹn, aṣiri ni. Orin la fi kọ, a fẹẹ ṣe ikojade orin ‘Wait for Me’ lakọtun tori awuyewuye to jẹ yọ lori ẹ. “Tẹlẹtẹlẹ lawọn eeyan ti n ro pe ọrẹbinrin mi ni, amọ emi atiẹ ko ti i sọ pe ‘Bẹẹ ni’ tabi ‘Bẹẹ kọ’ fun ara wa.”

Nigba to n sọrọ nipa iru ẹni ti Oloogbe Onwenu jẹ, King Sunny Ade ni: “Obinrin kan ti gbogbo wa ko le gbagbe nipa ẹ bọrọ ni. O ba mi lọkan jẹ pe ko duro jẹ pupọ ninu iṣẹ rere to ja fun loke eepẹ.

“Ọdun diẹ sẹyin ni ile-ẹjọ to ga ju lọ da a lare lori ẹjọ kan to da lori awọn awo orin rẹ ati ‘iṣẹ ọpọlọ’ rẹ. O dun wa pe a ti padanu obinrin naa bayii, amọ awọn nnkan aritọkasi to fi silẹ yoo maa wa ninu ookan aya wa titi.”

Tẹẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2024 yii, lawọn ọmọ bibi Onyeka Onwenu, Ọgbẹni Abraham Ogunlende ati Tijani Ogunlende, fidi ẹ mulẹ pe mama wọn ti mi eemi ikẹyin lọsibitu kan niluu Eko, l’ọgbọjọ, oṣu Keje, ọhun.

Wọn ni aarẹ ra-n-pẹ kan ni wọn tori ẹ gbe e lọ sọsibitu naa, amọ aisan lo ṣe e wo, ko sẹni to ri t’ọlọjọ ṣe.

Bi ITAFAAJI ṣe gbọ, inu oṣu Kẹjọ yii ni ireti wa pe wọn yoo sinku eekan olorin naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ko tii kede ọjọ ati akoko to maa jẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search