Itafaaji

Ọdun kan Iku Mohbad: Yọmi Fabiyi atawọn ọdọ fẹẹ ṣewọde nla n’Ikorodu

Bo tilẹ jẹ pe awọn mọlẹbi gbajugbaja ọdọmọde olorin hipọọpu to ku l’ọdun to kọja nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, t’awọn eeyan tun mọ si MohBad, ti l’awọn ko fẹẹ ṣe ayẹyẹ kankan lati sami ọdun kan ti ọmọ wọn ọhun d’ẹni akọlẹbo lojiji, sibẹ, eekan oṣere tiata ilẹ wa kan, to tun maa n ja fun ẹtọ ọmọniyan, Ọgbẹni Yọmi Fabiyi, ti ke sawọn ọdọ lati jade lọpọ yanturu fun iwọde alaafia, bẹẹ lo ti kọwe sileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, lati jẹ ki wọn mọ pe iwọde nla kan yoo waye lati ṣe iranti ọdun kan iku Mohbad, ati lati fi aidunnu wọn han si bi iwadii nipa ohun to ṣokunfa iku ojiji rẹ ọhun ko ṣe ti i foju han taara, ti awuyewuye iku ọhun ko si tii rọlẹ.

Ẹ o ranti pe ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 to kọja ni oṣere ti irawọ rẹ ṣẹṣẹ n tan yoo naa ṣadeede fo ṣanlẹ, to ku nile rẹ lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko, lẹyin ọjọ meji to lọọ ṣere fawọn ololufẹ rẹ lagbo ariya kan niluu Ikorodu.

Iṣẹlẹ agbọ-ju’gba-nu yii ya ọpọ eeyan lẹnu, o si bi ọgọọrọ awọn ọdọ ti wọn jẹ ololufẹ Mohbad ninu, titi kan awọn ajafẹtọọ-ọmọniyan kan, atawọn oṣere tiata ilẹ wọn, pupọ ninu wọn lo jade iwọde ati ifẹhonuhan nigba naa, wọn ni dandan ni ki ijọba wadii iku abaadi to pa Mohbad, tori iku naa mu ifura lọwọ, wọn si fẹ kijọba tan’na wo idi ọrọ ọhun, wọn fẹ ki wọn tu’ṣu de’salẹ ikoko lori rẹ.

Eyi lo mu ki ijọba Eko, ati ileeṣẹ ọlọpaa lọọ hu oku oloogbe naa lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 naa, lẹyin ọsẹ kan ti wọn ti sin in, lati le ṣayẹwo ijinlẹ si oku rẹ.

Amọ, lẹyin ọpọlọpọ oṣu, esi ayẹwo ọhun, eyi ti ọkan lara awọn akọṣẹmọṣẹ iṣegun, nileewosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti ipinlẹ Eko, Lagos State University Teaching Hospital (LASUTH), Dokita Ọjọgbọn Ṣokunle Sunday Ṣoyẹmi, to tun jẹ olukọ agba ni fasiti ipinlẹ Eko ṣe atupalẹ rẹ fun gbogbo eeyan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii niwaju kootu akanṣe to n ṣewadii iku Mohbad, iyẹn Corona Court of Inquest, eyi to wa ni Candide Johnson Courthouse, laduugbo Ita-Ẹlẹwa, niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, o ni iwadii ti wọn ṣe ọhun ko le fi pato ohun to ṣokunfa iku Oloogbe olorin naa mulẹ, tori awọn ẹya ara kan ti jẹra nigba tawọn fi lọọ hu oku rẹ, amọ ayẹwo wọn fihan pe kẹmika kan bayii, ti wọn pe ni Diphenhydramine, to jẹ ẹya antihistamine, eyi ti apọju rẹ le ṣe’ku paayan, wa lara Mohbad, amọ kinni naa ko pọ to eyi to le gbẹmi Oloogbe naa lojiji bẹẹ.

Ṣugbọn idile Alọba ti bẹnu atẹ lu esi ayẹwo ọhun, wọn lawọn ko gba, awọn ko si fara mọ ọn, wọn si ti bẹrẹ igbesẹ ayẹwo alapa meji mi-in ti ko ni i lọwọ ijọba ninu.

Ọjọ kejila oṣu Kẹsan-an to wọle de tan yii ni yoo pe ọdun kan geere ti Mohbad ku, Yọmi Fabiyi si ti fi ọrọ kan lede loju opo ayelujara Instagiraamu rẹ latari iranti iku oloogbe.

Ninu lẹta kan to kọ, to si buwọ lu lọjọ kejila, oṣu Kẹjọ yii, eyi to tẹ kọmiṣanna ọlọpaa Eko lọwọ lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹjọ yii kan naa, eyi ti ẹda rẹ tẹ ITAFAAJI lọwọ, Fabiyi ni kawọn ọdọ jade lọpọ yanturu, ki wọn ya bo ile-ẹjọ Coroner Inquest to wa n’Ikorodu lasiko igbẹjọ to n bọ, lati fi aidunnu wọn han, amọ iwọde alaafia ni o, o ni wọọrọwọ lawọn yoo yan bii ologun, ti wọn yoo si ẹdun ọkan wọn han. Bẹẹ lo ke sawọn ọlọpaa lati pese aabo fawọn lasiko iwọde naa.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search