Priscilla, ọmọ gbajumọ oṣere-binrin ilẹ wa nni, Iyabọ Ojo, rẹwa o si gbafẹ lori ẹrọ ayelujara. Ọpọ awuyewuye lo ti waye nipa ẹni ti ọmọbinrin naa fẹẹ fi ṣe ade-ori rẹ. Ni bayii, apọnbeporẹ naa ti tẹle ẹni tọkan rẹ yan, o ti mu ọkọ wale
Bi wọn ba n beere pe ta ni ọmọ ti wọn n sọ lọwọlọwọ, lasiko yii, koda bi wọn ko ba ju meji lọ, gbajugbaju oṣere tiata ilẹ wa ti ọrọ da lẹnu rẹ nni, Iyabọ Ojo, ati ọmọbinrin rẹ, Priscilla, yoo wa lara wọn.
Eyi ko ṣeyin bi ori ẹrọ ayelujara ṣe n ho ṣọṣọ fun oriire nla kan to wọle tọ Iyabọ Ojo lọsẹ ta a wa yii, ọmọ rẹ Priscilla lo mu ọkọ wale, o waa foju afẹsọna rẹ, Ọgbẹni Juma Jux, han, wọn si ṣe mọ-mi-n-mọ-ọ fẹẹrẹfẹ, Iyabọ Ojo gba ọmọkunrin naa wọle, tọkọ-taya ọla naa si n dunnu bi wọn ṣe n wo ọjọ igbeyawo wọn lọọkan.
Ṣe bi ina n jo loko, majala ni i ṣe ofofo, lati bii ọjọ meloo kan ni awọn ololufẹ oṣerebinrin naa ati awọn ti wọn n tẹle ọmọbinrin arẹwa rẹ ọhun lori ikanni ayelujara ti n fura, ti wọn si n wo ṣakun gbogbo bi nnkan ṣe n lọ, pẹlu oriṣiiriṣii ọrọ ifẹ ati fọto ti ọmọbinrin naa n gbe soju opo Instagiraamu rẹ, eyi lo mu kawọn aye fura pe afaimọ ni Priscilla ko ni i di oloruka laipẹ, wọn lo jọ pe o ti pade ololufẹ kan ti yoo ja ododo rẹ lagbala iya rẹ.
Ni nnkan bii oṣe kan ṣaaju asiko yii ni Priscilla ti kọkọ gbe ọrọ kan soju opo Instagiraamu rẹ, o ni “Aye ẹ ni o, ohun to ba ti wu ẹ ni ko o ṣe”, o si kọ ọrọ mi-in sabẹ fọto dudu naa pe “Ọmọ yii ti di ololufẹ ẹnikan”. Bẹẹ gan-an si lọrọ ọhun pada ja si nigba to di ọjọ keji, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 ta a wa yii, ọjọ naa ni ọkọ afẹsọna Priscilla foju hande. Onkọrin taka-sufee ọmọ bibi orileede Tanzania lọmọkunrin naa, Juma Jux, oun lo ti n pa kubẹkubẹ pẹlu ọmọ Iyabọ Ojo labẹlẹ, ọkunrin yii lo kọ orin ti wọn pe akọle rẹ ni “Sugar” laipẹ yii, orin naa si gbajumọ lagbo awọn to fẹran hipọọpu daadaa.
Lọgan ti Iyabọ Ojo, tawọn ololufẹ rẹ tun maa n pe ni Iya Ọmọọba-binrin, tabi Queen Mother lede eebo ti ṣe ikede yii lawọn onitiata ẹlẹgbẹ rẹ atawọn ololufẹ rẹ ti n ki i ni mẹsan-an mẹwaa, ti wọn si n sure fun un pe o kuu oriire, ati pe ayọ naa yoo ba a kalẹ, yoo si ri ere nibẹ.
Ọkan ninu awọn onitiata ti ko le pa idunnu rẹ mọra ni Mercy Aigbe, o kọ ọrọ sabẹ ikede naa, o ni: “Bẹẹ ni o, wọn ti mu ọmọbinrin mi lọ. A kuu oriire, ifẹ mi, Priscilla, ati ana wa Juma Jux. A fi tifẹtifẹ gba yin tọwọ-tẹsẹ. Awa o ki i fi awọn ọmọbinrin wa ṣere o, amọ a fọkan tan ẹ. Mo gbadura ki ẹyin mejeeji maa ṣaṣeyọri ninu alaafia, ayọ, ẹrin ati ibukun ti ko lopin.”O tun sọ pe: “Si iwọ Iyabọ Ojo, mo ki ẹ kuu oriire o, ọrẹ. O ṣe daadaa gan-an, mo si fi ẹ yangan. Ọrẹ Iya Iyawo ti de o.”
Lori ikanni Priscilla, iyawo lọla, ọrọ naa ko yatọ. Tidunnu-tidunnu l’ọmọbinrin apọnbeporẹ naa fi gbe awọn fọto oun ati afẹsọna rẹ soju opo ayelujara rẹ, wọn jọ wọ aṣọ ginni to n dan bii ẹyin aayan, alawọ pupa to rẹ dodo kan, bẹẹ n’iyawo mu abẹbẹ igbalode ti wọn kọ orukọ rẹ si lara, dani, bi ọkọọyawo ṣe n rẹrin-in ẹyẹ, bẹẹ ni iyawo naa n boyin kẹ-ẹn, ti ayọ si han loju awọn mejeeji. Priscilla si kọ ọrọ ṣoki sabẹ fọto naa, o ni: Ololufẹ mi! O si fi awọn ami ifẹ sibẹ.
Gbajumọ onitiata mi-in, Mercy Johnson ni: “O kuu oriire o, Iya Iyawo.”
Angela Okorie ni tiẹ kọ ọ sibẹ pe: “Mo ba a yin yọ o, Aunti Alice, Isopọ yii aa dalẹ o. Awọn mejeeji ba ara wọn mu dọba. Mo ba a yin yọ, ẹ ko ni i kabaamọ lori wọn o, Amin.
Bimbọ Ọṣhin sọ pe: ỌOluwa yoo ba yin rin irinajo ifẹ yii o, onitemi. O rẹwa lati ri ẹyin mejeeji.
Onitiata mi-in, Nkechi Blessing Sunday ni: “Inu mi dun gidigidi si eyi.”
Bukunmi Oluwaṣina ni tiẹ sọ pe: “Ẹ kuu oriire o. Ọlọrun ti bu kun irin-ajo ifẹ yin o.
Aka-i-ka-tan ni awọn ololufẹ Iyabọ ati ọmọbinrin re ti wọn kọ ọrọ idunnu si wọn lori iṣẹlẹ yii, bẹẹ ni wọn n rọjo adura ni ọlọkan-o-jọkan, bo tilẹ jẹ pe ọrọ ikilọ lawọn mi-in kọ ṣọwọ si ọmọbinrin naa, wọn ni ile ọkọ, ile ẹkọ ni.