Itafaaji

Idije ẹṣẹ kikan: Daniel maa fọ Joshua lẹnu pẹtẹpẹtẹ ni o – Frank

Ilumọ-ọn-ka onigbọwọ awọn abẹṣẹẹku-bi-ojo kan, Ọgbẹni Frank Warren ti sọ asọtẹlẹ nipa idije ẹṣẹ kikan to maa waye laipẹ si asiko yii laarin abẹṣẹẹku-bi-ojo ọmọ bibi Naijiria kan Anthony Oluwafẹmi Ọlaṣeni Joshua, tọpọ eeyan mọ si Anthony Joshua ati alatako rẹ, Daniel Dubois, o ni Daniel ni yoo jawe olubori idije naa, tori o da oun loju pe niṣe ni yoo fọ Anthony lẹnu pẹtẹpẹtẹ.

Joshua ati Daniel
Papa iṣere Wembley

=========
Papa iṣere Wembley Stadiun, to wa niluu London, lorileede United Kingdom ni awọn abẹṣẹẹku-bi-ojo mejeeji yii yoo ti wa a ko lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii, lati mọ ẹni ti yoo fi ọga han ekeji rẹ. 

Ọjọ naa ni Daniẹl yoo kan ẹṣẹ lati gbeja ami-ẹyẹ ẹni to mọ ẹṣẹ i kan lagbaye ti ajọ International Boxing Federation fun un, yoo si gbe’na w’oju Anthony Joshua, ọmọ bibi ipinlẹ Ogun, to ti gba ami-ẹyẹ abẹṣẹẹku-bi-ojo to fakọyọ lagbaye, nipele awọn agba-ọjẹ kanṣẹ-kanṣẹ, lẹẹmeji ọtọọtọ.

Anthony
Warren
Dubois
Wembley

Ọgbẹni Warren, ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin, sọ fawọn oniroyin ori ẹrọ ayelujara kan, BoxingScene, pe oun ko mikan lori Daniel, o lọkan oun balẹ pe yoo fẹṣẹ dara si alatako rẹ, iyẹn Anthony Joshua lara, yoo si fẹyin rẹ balẹ.

Warren ni: “Ṣikun ni Joshua maa n ko sawọn alatako rẹ lọwọ, ẹ si jẹ ki n sọ nnkan kan fun yin, ibi tọrọ tiẹ wa niyẹn.
Ṣe ẹ ri i, ẹni ti ẹṣẹ ba kọkọ ṣe leṣe ju, bi tọhun ba ṣe tete dahun pada, lo maa sọ bi ija naa yoo ṣe lọ. Awọn ojo ẹkẹṣẹ to ba kọkọ rọ, bi ẹni to ba ba ṣe fesi ni koko, ki i ṣe ọrọ pe ka kan lu-u-yan lalubami lasan.”

Ọkunrin naa sọ asọtẹlẹ pe o ṣee ṣe ki Joshua maa sa kijokijo lati yẹ ẹṣẹ alatako rẹ, iyẹn si ni ohun to maa jẹ ki eegun alatako naa ran si i, ti yoo fi han an leemọ daadaa. O ṣe tan, lẹnu aipẹ yii, Daniẹl, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn yii ṣe daadaa ninu awọn idije kan to ti kopa, o ni afaimọ ni ko ni i gbo ewuro soju Joshua, lai fi ti iriri ati agbara Joshua pe.
Ko si ani-ani pe ọgọọrọ awọn ololufẹ idije ẹṣẹ kikan ni wọn n foju sọna fun idije to fẹẹ waye laarin Joshua ati Daniẹl yii, latari bo ṣe jẹ pe awọn oludije mejeeji ni wọn ni ẹṣẹ gba-kan-o-ṣubu lọwọ, ti wọn si ti fakọyọ ninu itaporogan ti wọn ti kopa sẹyin. Eyi lo mu kawọn ololufẹ wọn gbogbo maa haragaga lati mọ ẹni ti yoo fi agba han ekeji rẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search