Romance between veteran actor Bisola Badmus and the renowned Fuji music star, Wasiu Ayinde, KWAM 1, produced a boy, Malik. Eniola had a reason to call Wasiu Ayinde out recently

Itafaaji

Ṣ’ẹyin naa ti gbọ ohun to ṣẹlẹ laarin Bisọla Badmus ati Wasiu Ayinde?

Ilumọ-ọn-ka arẹwa oṣere tiata, obinrin bọrọkọtọ bii ọka nni, Bisọla Badmus, sọ iwa ti baba ọmọ rẹ, Wasiu Ayinde KWAM 1 hu si i, lori ọmọ wọn, Malik, o si parọwa si i

Bisola ati Wasiu, Malik ati iya rẹ ninu akamọ
Bisọla Badmus
Bisọla ati Biọla Adebayọ lasiko ifọrọwerọ

Gbajumọ oṣere tiata ilẹ wa apọnbeporẹ nni, Bisọla Badmus, ti figbe bọnu lori ẹrọ ayelujara, lati pe akiyesi gbogbo awọn ololufẹ rẹ si ọrọ baba ọmọ rẹ, toun naa gbajumọ daadaa to si jẹ eekan oṣere ati olorin Fuji nilẹ yii, Oloye Wasiu Ayinde Ọmọgbọlahan, tawọn eeyan mọ si KWAM 1 tabi K1. Bisọla fẹsun kan KWAM 1 pe ko bikita nipa ọmọ ti oun bi fun un, o ni k’awọn aye ba oun bẹ Wasiu Ayinde ko waa tọju Malik, ọmọ ẹ.

Ninu ifọrọwerọ kan ti Iya Malik ṣe pẹlu oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ kan, Biọla Adebayọ, lori ẹrọ ayelujara, lọsẹ ta a wa yii, nibẹ ni Bisọla ti tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ nipa ina to n jo o labẹ aṣọ, bi aisan buruku kan ṣe ba a finra fun ọpọ ọdun, ati awọn adujukọ mi-in to ri lori itọju ọmọkunrin to bi fun Wasiu Ayinde, Malik.

Wasiu Ayinde Ọmọgbọlahan, K1

Ṣe Yoruba bọ, wọn ni ijo to ba ka ni lara la a di’ṣẹ jo, ọwọ to n dun’ni ko si ṣe e tọju sabẹ aṣọ, boya eyi lo mu ki Bisọla Badmus sọrọ soke nipa baba ọmọ rẹ yii.

Bayii lo ṣe sọrọ naa, o ni: “Ọmọ daadaa ni ọmọ yẹn, Malik. Ohun toju ẹ ti ri, oun gan-an ko le ro pe oun maa tete ri i ni kekere. Amọ o ni agbesara. O duro ti mi, o ni laakaye gidigidi, o ri ẹ pe pupọ, ọlọgbọn ọmọ si ni.

Wasiu, Oluaye Fuji

“K1, iyẹn Wasiu Ayinde ti mo bimọ yii fun, iwọnba ifẹ lo fi han si ọmọ ẹ ọhun. Lati bii ọdun mẹta sẹyin ni mo ti ni ailera ọyun inu ọpọlọ tawọn eleebo n pe ni brain tumor. Loootọ, Wasiu ko kọkọ mọ nipa adojukọ ti mo ni yii o, nitori mi o sọ fun un. Nigba to si gbọ si i, o gbiyanju ohun to le ṣe fungba diẹ, amọ ko da si mi mọ nigba to ya.

“Ohun ti mo sa fẹ ni bayii ni pe ko gbọ bukata lori ọmọkunrin wa. Apa ti n kun mi bayii lati maa ṣe adagbe adasọ lori gbogbo nnkan, paapaa nigba ti ailera mi yii ṣi wa sibẹ.

Bisola Badmus ati Malik, ọmọ rẹ
Wasiu, KWAM 1

“Ohun ti mo n fẹ latọdọ K1 ni ko ṣe ojuṣe ẹ lori Malik, ọmọ ẹ. Mo fẹ ko tọju ọmọ ẹ yii daadaa o.” Ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O daju pe ọrọ ti iya ọmọ Oluaye Fuji yii sọ ti de etiigbọ rẹ, bo tilẹ jẹ pe Wasiu Ayinde ko ti i fesi pato kan si ẹsun ti Bisọla Badmus fi kan an yii. Oniroyin kan pe agbenusọ KWAM 1, Ọgbẹni Kunle Rasheed, lori aago ọkunrin naa fesi pe: “Emi ati ọga mi ko tii sọ ohunkohun nipa ọrọ yii, a o tii raaye sọrọ nipa iru nnkan bẹẹ. Nitori naa, mi o tii le fesi nipa ẹ afi ti mo ba kọkọ ba KWAM 1 sọrọ na. Amọ mi o sẹ iṣẹlẹ yẹn, mi o si sọ pe ẹsun naa jẹ ootọ tabi irọ. Ẹ sa ṣe suuru 

Odu ni Ẹniọla Badmus lagbo awọn oṣere tiata, ki i ṣe aimọ fun oloko rara. Ọmọ bibi ipinlẹ Ogun yii fakọyọ ninu ọgọọrọ fiimu to ti kopa, lara awọn ere to gbe ogo rẹ jade ni eyi ti wọn pe akọle rẹ ni Olokiki Oru, Akoto Ọlọkada, Igbeyawo Arugbo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search