Itafaaji

Anthony Joshua sọrọ lori bo ṣe fidi rẹmi niwaju Dubois abẹṣeẹ-ku-bii-ojo

Latari bo ṣe fidi rẹmi niwaju Daniel Dubois, awọn eeyan kan ti n sọ pe Anthony Joshua ko ni i kanṣẹ mọ. Amọ ọkunrin naa ti sọrọ, o fi erongba rẹ han lori alatako rẹ, ati igbesẹ toun fẹẹ gbe.

Ilumọ-ọn-ka abẹṣẹẹku-bii-ojo ọmọ bibi orileede Naijiria nni, Anthony Joshua, ti sọrọ lori bo ṣe fidi rẹmi ninu idije ẹṣẹ kikan kan to waye lorileede United Kingdom lopin ọsẹ to kọja yii, nigba toun ati alatako rẹ, Daniel Dubois yọ ọwọ ẹṣẹ si ara wọn, Joshua ni ifidirẹmi oun ko tumọ si pe oun maa jawọ ninu ere idaraya toun yan laayo yii, amọ agbo oun yoo ṣi tadi mẹyin na, lati le lọọ mu agbara wa lakọtun.

Ẹ o ranti pe fọfọ ni papa iṣere Wembley Stadium kun fun ero onworan to le ni ẹgbẹrun lọna mejidinlọgọrun-un (98,000) laṣaalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Ọ̀wẹ́wẹ (September), ọdun 2024 yii lati mọ ẹni ti yoo fagba han ẹnikeji laarin Anthony Joshua, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34) to ti n kan ẹṣẹ bọ lati bii ọdun mẹrinlelogun (24) sẹyin, ati ọdọmọkunrin to pe e nija, Daniel Dubois, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27) pere.

Ṣaaju ki idije naa too waye lawọn ololufẹ ere ẹṣẹ kikan ti pin ara wọn sọna meji, bi awọn kan ṣe n sọ pe ko sọna ti Daniel yoo gbe e gba niwaju Joshua ti ko nii ge’ka abamọ jẹ, nitori o da awọn loju pe pẹlu iriri ọdun pipẹ ati ipo ti Joshua wa, gẹgẹ bii ẹni to ti gba ife ẹyẹ ẹṣẹ kíkàn nipele ti awọn agba ọjẹ abẹṣẹẹku-bii-ojo lẹẹmẹta ọtọọtọ, yoo fun un lanfaani lati fẹṣẹ yọ eyin alatako rẹ, wọn ni bii aayan to kagbako epo idana kẹrosiini lọrọ rẹ yoo jẹ, bẹẹ lawọn ti wọn jẹ ololufẹ ọjafafa abẹṣẹẹku-bii-ojo Daniel Dubois n fọwọ sọya pe ẹja to n da ibu omi ko ju apa lọ ni tọrọ ọdọmọkunrin naa, wọn lo san-an-gun daadaa ju Anthony lọ, ati pe ara rẹ ta pọun-pọun, o si jafafa gidi, wọn lo maa ṣe Anthony bi ọṣẹ ṣe n ṣe oju ni.

Oleksandr Usyk
Isreal Adesanya
Tyson Fury
Frank Warren

Bi ọjọ idije naa ṣe n sun mọle ni awuyewuye naa n le si i, ọrọ ọhun ko si yọ awọn agba-ọjẹ kanṣẹ-kanṣẹ, awọn onigbọwọ atawọn alẹnulọrọ lagbo ere idaraya silẹ, lara wọn ni Oleksandr Usyk ati Tyson Fury, Abẹṣẹẹku-bii-ojo ọmọ Naijiria mi-in Isreal Adesanya, Ọgbẹni Frank Warren toun jẹ onigbọwọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Amọ nigba tawọn mejeeji dori ọdan, ọrọ bẹyin yọ, lati ibẹrẹ ni idije naa ni Anthony Joshua ti n ja fitafita pẹlu ojo ẹṣẹ gba’kan-o-ṣubu to n bọ lu u lara. Ẹẹmẹrin ọtọọtọ ni Daniel fẹyin Joshua balẹ, to si rọjo ẹṣẹ lu u lalubami, ọpẹlọlọpẹ oludari idije naa to tete da ọkunrin ọhun lọwọ kọ.  Nigba to di ipele karun-un, o han gbangba pe ifa ko fọ’re fun Joshua latari bi Daniẹl ṣe tun le’wọ ẹṣẹ si i, o f’ẹṣẹ fọ ọ lẹnu, o si fi ẹyin rẹ balẹ. Koda, Joshua fi ẹmi oludije rere han, tori o gboṣuba fun alatako rẹ yii, o loun gba pe o fakọyọ, ẹẹmeji lo fọ ede Gẹẹsi, o ni “well played”.

Eyi ni yoo jẹ igba keji ti Anthony Joshua yoo ṣubu yakata niwaju alatako rẹ lasiko idije pataki bii eyi, ọrọ naa lo si mu kawọn eeyan maa sọ pe o ti n rẹ ọkunrin naa, wọn niṣe ni yoo lọ wabi jokoo si jẹẹjẹ lati asiko yii lọ, amọ Joshua ti sọrọ soke, o ni ko sohun to jọ ọ, oun yoo lọọ tun ara mu ni.

Nigba ti awọn oniroyin ere idaraya kan bi i leere boya o ṣi n gba a lero lati tun ija ọhun ja lọjọ iwaju, lọgan ni Anthony fesi pe “Bẹẹ ni o, a o kunju oṣuwọn lasiko yii, amọ jagun-jagun ni mi, a maa tun ija ja ni, bi ẹṣin ba da ni, niṣe la a tun un gun.”

O fi kun un pe: “Ni bayii, idije yii ti pari, mo si ṣi fila mi fun un, iṣẹ lo ṣe, o kare gidi”. Bayii ni Anthony Joshua sọ o.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search