Itafaaji

Iku MohBad: Yọmi Fabiyi atawọn ọdọ maa ṣewọde nileegbimọ aṣofin

Yoruba bọ, wọn ni bi ina ko ba tan laṣọ, ẹjẹ ko nii tan leekanna, bi ẹni a n pe ko ba si ti i dahun, ẹni to n peni ko nii sinmi ariwo, ọrọ yii lo wọ bi iwọde itagbangba mi-in ṣe fẹẹ waye lori iku gbajugbaja ọdọmọde onkọrin hipọọpu nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan mọ si Mohbad, lọtẹ yii, ileegbimọ aṣofin Eko, ni awọn ọdọ pinnu lati ko rẹi-rẹi lọ, lati beere fun idajọ ododo lori iku ololufẹ wọn olorin taka-sufee ọhun.

Ilumọ-ọn-ka oṣere tiata ilẹ wa kan, Yọmi Fabiyi, to tun n ṣiṣẹ ajafẹtọọ-ọmọniyan lo ṣagbatẹru iwọde ati ifẹhonuhan ọhun, oun ni yoo si lewaju awọn ọdọ lati lọọ fi ẹdun ọkan wọn han sawọn aṣofin ipinlẹ Eko lọjọ to gbẹyin oṣu yii, iyẹn ọgbọnjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024. Ninu atẹjade kan ti Yọmi fi ṣọwọ si akọroyin ITAFAAJI lori ẹrọ ayelujara lọjọ Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹsan-an yii, Yọmi ni “Ẹ jẹ kẹsẹ wa pe ṣiba ṣiba sileegbimọ aṣofin Eko, lati ja fun idajọ ododo lori iku Mohbad. A fẹ kẹyin oluyọnda-ara-ẹni, ẹyin ajafẹtọọ-ọmọniyan gbogbo, ati ẹyin ọdọ darapọ mọ wa laago mẹjọ aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọgbọjọ oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024.” 

Ẹwu didu kirikiri ni aṣọ ti wọn dabaa pe kawọn oluwọde naa wọ.

Lori ikanni ayelujara Instagiraamu rẹ, Yọmi Fabiyi ṣalaye idi ti iwọde naa fi ṣe pataki ati bi yoo ṣe lọ si. Ọkunrin to gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta lagbo awọn onitiata yii sọ pe awọn ọbayejẹ ti wọn wa nidii iku oro to pa MohBad ti wa lominira, wọn n jaye ori wọn kiri, wọn si n nawo bii ẹlẹda lati ri i pe aṣiri iku ojiji to pa Imọlẹ di titẹri, tori ẹ, niṣe ni wọn n fi ẹtẹ silẹ pa lapalapa, ti wọn si n ṣe nnkan to le da oju ẹjọ ru.

Yọmi Fabiyi ni ẹrọ kamẹra aṣofofo, iyẹn CCTV to wa ni tinu-tode ile ti Mohbad n gbe ko daṣẹ silẹ lasiko iku rẹ, o ni kamẹra naa n ṣiṣẹ, ati pe gbogbo ofofo ti kamẹra naa ṣe wa ni kika silẹ nipamọ lọwọ ẹnikan ti ko gbe inu ile ọhun, ati eyi ti wọn tọju sori ẹrọ DVR. O lo yẹ kijọba fọrọ wa awọn to kọ iru ile ti MohBad n gbe yii, atawọn eeyan inu ẹsiteeti tile ọhun wa lẹnu wo, tori gbogbo wọn ni ibi ti aṣiri iku to pa oloogbe naa ha si. Yọmi, tawọn eeyan tun n pe ni Araba, sọ pe bi ko ba ni ọwọ kan abosi ninu, oun ko mọ idi tawọn ọlọpaa ko fi fẹẹ tuṣu desalẹ ikoko lori iku oloogbe yii.

“O ṣe pataki ka ṣe iwọde wọọrọwọ, iwọde alaafia lẹnu geeti ileegbimọ aṣofin Eko, lọgbọnjọ oṣu Ọwẹwẹ (September) ọdun 2024 yii. Awọn ti wọn da ẹmi Mohbad legbodo, wọn n nawo nara lati bo otitọ ati aṣiri iku to pa a mọlẹ. 

A fẹ kawọn agbofinro fọrọ wa awọn to kọ ile to wa ni Royal Pine Estate, nitosi ọna Orchid, awọn eleto aabo Lekki ati awọn igbimọ idagbasoke adugbo (CDA) lẹnu wo, ki wọn lu gbogbo wọn lẹnu gbọrọ, wọn aa mọ ibi ti wọn bo aṣiri iku ojiji naa mọlẹ si.” Yọmi lo sọrọ bẹẹ lori ikanni rẹ.  

Ẹ o ranti pe iru iwọde lati pe fun idajọ ododo lori iku Mohbad bẹẹ ti waye lọjọ kọkanla oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, to ṣe kongẹ pẹlu ajọdun ọdun kan iku Oloogbe ọhun. Ilu Ikorodu, niwaju ile-ẹjọ to n ṣewadii ẹsun iku Mohbad, to fikalẹ si agbegbe Ita-Ẹlẹwa, niluu Ikorodu ni wọn ti ṣewọde naa, Yọmi Fabiyi lo si ṣagbatẹru rẹ bakan naa.

Titi dasiko yii ni iwadii ijinlẹ ṣi n tẹsiwaju lati tọpinpin ohun to pa Mohbad lojiji loṣu Kẹsan-an ọdun 2023.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search