Itafaaji

Bi mo ṣe pa okoowo pọ mọ ere tiata yii, oju mi ri to! – Mercy Aigbe

Yoruba bọ, wọn ni ẹni ti ko gbọ tẹnu ẹga ni yoo sọ pe ẹyẹ oko n pàátó. Irawọ oṣere tiata ilẹ wa to rẹwa bii egbin nni, Mercy Aigbe ti gba awọn oniṣowo atawọn oṣere ẹlẹgbẹ lamọran. Amọran naa da lori ohun to n la kọja nidii iṣẹ tiata ati okowo to n ṣe papọ. Ọrọ kan, adura kan ni.

Mercy Aigbe ree nidii okoowo rẹ

Mercy Aigbe, agba-ọjẹ oṣere-binrin onitiata ilẹ wa to rẹwa daadaa nni, ti sọrọ nipa iriri rẹ nidii iṣẹ ere ori itage ati okoowo to mu mọ iṣẹ naa, o ni kinni naa ko rọrun rara, bii ọrọ ẹni maa jẹ oyin inu apata ti ko ni i wo ẹnu aake ni.

Oṣere yii fi erongba rẹ ọhun han ninu ọrọ kan to gbe sori ikanni ayelujara rẹ laipẹ yii, nibi to ti n gba awọn oṣere ẹlẹgbẹ rẹ ati gbogbo awọn to ṣe okoowo kan tabi omi-in, agaga lorileede Naijiria lamọran, o ki wọn daadaa, o gboṣuba nla fun wọn, o si fun wọn niṣiiri pe ki wọn maṣe kaarẹ ọkan nidi iṣẹ aje ti koowa wọn yan laayo.

Ṣe adiyẹ n laagun, iyẹ ara rẹ ni ko jẹ ka mọ, gẹgẹ bi owe Yoruba ṣe sọ, Mercy Aigbe ni ohun toun n foju wina rẹ lati le wa deede, koun si le kogo ja nidii okoowo oun, pẹlu iṣẹ tiata ti gbogbo aye ti mọ oun mọ latilẹ ko kere rara, iso inu ẹku loun n fi ọrọ naa ṣe nigba mi-in, amumọra ni.

Bayii ni gbajumọ onitiata to jẹ iyawo lọọdẹ ọkunrin gbajumọ onigbọwọ awọn oṣere kan, Alaaji Kazeem Adeoti ṣe sọ ọrọ to pe akọle rẹ ni BI IGBESI AYE ṢE RI LASIKO YII, o ni:

“Mo kan saara si gbogbo awọn olokoowo lorileede Naijiria lasiko yii o. Lai fi ti oniruuru ipenija ti wọn n koju latari pakaleke ọrọ-aje ati ọwọngogo ọja ṣe, wọn sa rọku sidi ẹ naa ni. Iriri yii kii ṣe keremi o! Keeyan da okoowo silẹ ni Naijiria ko yatọ si keeyan maa pọn oke giga apatapiti kan, o gba gbogbo suuru ati ifayaran yin. Pẹlu gbogbo ẹ naa, mo ti kẹkọọ pe eeyan gbọdọ tẹsiwaju bo ṣe n la iji aye kọja lọ ni.

Gẹgẹ bii oniṣowo, bi mo ṣe pa karakata mọ iṣẹ fiimu ati tiata ṣiṣe mi ko dẹrun rara, amọ mi o jẹ ko rẹ mi, oun lo jẹ ki n le maa gba ẹyin naa lamọran lati maṣe kaarẹ ọkan. Ẹ maa lepa bi ala rere yin ṣe maa nimuuṣẹ, kẹẹ si maa ranti pe ki oṣumare rirẹwa to o jade, iji ati ojo yoo ti waye.

 

Ẹ ma jẹ ko rẹ yin o! Nibi ta a ti ba a de yii, ṣe ẹ fẹẹ gbọ ootọ ọrọ lẹnu mi, asiko ikore ti de tan. Mo gbadura pe k’Ọlọrun jẹ ka ṣaṣeyọri, ka si kore rẹpẹtẹ.

Ọrọ ti mo kọ yii, mo fẹẹ ko jẹ iṣiri fun gbogbo yin, bo ṣe n jẹ iṣiri fun emi alara. Ki Ọlọrun mu wa la saa yii ja, ka le maa tẹsiwaju niṣo laika ohunkohun to le ṣẹlẹ si.”

Ilumọ-ọn-ka ni Mercy Aigbe lagbo awọn oṣere tiata ilẹ wa, ojo si ti n pa igun rẹ bọ, ilẹ ti ta si i. Apọnbeporẹ ọmọ bibi ipinlẹ Edo, ni iha Guusu ilẹ Naijiria jẹ oṣere to da-n-tọ, to si maa n fi gbogbo ara ṣere itage, bii ede oyinbo ṣe yọ lẹnu rẹ, bẹẹ lo gbọ ede Yoruba doju ami, towe-towe taṣamọ-taṣamọ.

Lọdun diẹ sẹyin lo mu okoowo aṣọ, bata, atawọn ohun eelo iṣaraloge pọ mọ iṣẹ tiata rẹ, nigba to ṣi ileetaja to pe orukọ rẹ ni Mag-Divas Boutique siluu Eko ati Ibadan, nipinlẹ Ọyọ. Ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta ni Mercy Aigbe.

mercy aigbe boutique
Ọkan lara ileetaja rẹ

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search