Oṣere tiata to rẹwa, to si jafafa nidi iṣẹ rẹ ni Ẹniọla Badmus. Bi ọrọ ṣe da ṣaka lẹnu rẹ ninu fiimu, bẹẹ naa ni loju aye, kii bẹru lati sọ oju abẹ nikoo. Amọ, laipẹ yii lo sọrọ kan nipa bi eto ọrọ-aje orileede Naijiria ṣe n lọ si labẹ ijọba Aarẹ Bọla Tinubu yii. O jọ pe ọrọ naa bi ọpọ eeyan ninu gidigidi.
Ẹniọla Badmus, to jẹ Oludamọran pataki lori eto ariya ati faaji si olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin apapọ l’Abuja, Ọnarebu Tajudeen Abass, ni, ni toun o, adinku to ti de ba kiko ọja wọle lati ilu oyinbo, ti wọn n pe ni imports, ti eto kiko ọja ilẹ wa lọọ ilu oyinbo si ti pọ si, iyẹn exports, o ni ami gboogi kan leyi jẹ lati fihan pe eto ọrọ-aje ilu yii n tẹsiwaju, o si n tobi si i.
Ẹniọla ko sọrọ naa ṣakala bẹẹ, o mu gege rẹ, o si fi iṣiro balẹ, o ni ta a ba mu ọdun 2024 ta a wa yii nikan, owo to ba kiko ọja wọlu lati ẹyin odi lọ, o le ni tiriliọnu mẹrinlelogun naira (N24.44 trillion) nigba ti owo kiko ọja jade din diẹ ni tiriliọnu mejidinlogoji naira (N38.59 trillion), eyi to fi tiriliọnu mẹrinla yatọ si ara wọn.
Wule Bantu waa pari ọrọ rẹ, o ni “iru eyi ko tii ṣẹlẹ ni Naijiria yii ri. Ko tiẹ ṣẹlẹ ri rara ni. O si mu ọkan ẹni yọ pe a ti n sun kẹrẹkẹrẹ kuro ni orileede to maa maa duro de nnkan oyinbo, awa naa ti n pese nnkan ta a le ta sẹyin odi.”
Amọ ko jọ pe ọrọ ati alaye Ẹniọla Badmus yii tẹ awọn ololufẹ rẹ lọrun rara. Ọpọ awọn to fesi lori ohun to kọ naa ni wọn bu u, ti wọn si ṣaata rẹ.
Ẹnikan ti ko kọ orukọ ara ẹ ni: “Too, bawo waa ni gbogbo eyi too sọ yii ṣe nipa lori igbe aye araalu? O jẹ gbẹnu ẹ dakẹ ti oo ba mọ ohun yẹ ko o sọ”.
Ẹlomi-in tun ni: “Ko si irọ tẹnikẹni o le pa nipa ohunkohun. Iwọ naa wo ayika ẹ ko o le ri i boya nnkan n dara si i ni abi o n bajẹ si i.”
Ẹnikan tun beere pe: “Ẹniọla, eelo ni wọn gbe fun lati sọ ohun ti o sọ yii. Airikan-ṣekan n yọ ẹ lẹnu.”