Itafaaji

Ẹwa obinrin: Gele ko dun bii ka mọ ọn we…

Ọkan ninu owe Yoruba to gbajumọ daadaa lọ bayii: Gele ko dun bii ka mọ ọn we, ka mọ ọn we ko da bii ko yẹ’ni. Owe yii fihan pe to ba di ọrọ oge ṣiṣe, ẹwa ati imura, gele ko ipa pataki, nitori o maa n ṣe alekun ẹwa awọn obinrin, ọkan pataki ninu aṣa imura ilẹ Yoruba si ni.
Bi fila ṣe ri si imura ọkunrin, bẹẹ naa ni gele. Bo ṣe yẹ ki ọkunrin mọ fila i gẹ, bẹẹ lo ṣe yẹ ki obinrin to ba gbọ faari mọ gele i we. O ṣe tan, gigẹ la n gẹ fila, wiwe la n we gele. Ẹsẹ orin awọn ẹlẹmu kan tiẹ sọ pe: ọkunrin lo ni fila, obinrin lo ni gele, ọmọ ẹlẹmu lo lẹmu.

Ki ni wọn n pe ni gele? Bawo ni wọn ṣe n we e? Ipa wo lo si ni lori imura ati oge ṣiṣe nilẹ Yoruba?

Laye atijọ, iro ati buba lo wọpọ ninu aṣọ tawọn obinrin maa n wọ, oun si ni wọn maa n ran ju lọ. Amọ ni gbogbo igba ti wọn ba ran iro ati buba, wọn maa sọ fun aranṣọ wọn pe ko yọ ìborùn, ko yọ ìpèlè, o si gbọdọ yọ gele ninu aṣọ naa, aijẹ bẹẹ, imura naa ko pe. Ibi ti ọrọ gele ti yatọ ni pe, nigba ti iborun gbọdọ dọgba pẹlu aṣọ ti wọn ran ọhun, ko pọn dandan ko jẹ oriṣii aṣọ ti wọn fi ran iro ati buba ni gele rẹ yoo jẹ. Nigba mi-in, gele le jẹ oriṣii aṣọ mi-in to yatọ patapata, amọ awọ rẹ jọra pẹlu iro ati buba naa. Bii apẹẹrẹ, o le jẹ aṣọ ankara tabi teru ni wọn fi ran iro ati buba, o si le jẹ aṣọ adirẹ, amọ gele ti wọn yoo we si i le jẹ aṣọ ofi, eyi ti wọn tun maa n pe ni aṣọ oke.

 

Nigba ti ọlaju de, ti awọn aṣọ ilu oyinbo bẹrẹ si i wọn ilẹ wa, awọn oriṣii aṣọ kan wa ti wọn diidi ṣe lati fi we gele. Awọn aṣọ naa maa n gan paali bii ẹja inu yinyin ni, yoo si maa dan bọrọbọrọ. Iṣẹ nla ni lati we e, nitori ki i ṣe aṣọ rirọ bii aṣọ ofi ti wọn n hun nilẹ wa, amọ oriṣii gele yii maa n rẹwa, o si maa n pe afiyesi si ẹni to ba we e, latari bi yoo ṣe ri rente-rente lori onitọhun. Ibi ti wọn ba we e si ni yoo duro si.

Iyatọ wa laarin gele ati ibori. Ibori wulẹ jẹ aṣọ kan tawọn obinrin maa n ta mọ ori wọn. Loootọ wọn le lo ibori lọ sode ayẹyẹ nigba mi-in, amọ ibori ki i ṣe alekun ẹwa bii gele. Ibori yii ni wọn n pe ni sikaafu lede oyinbo. Eeyan le lo ibori bii aṣọ iwọle, aṣọ iṣere, amọ gele ko ṣe e lo bẹẹ. Imura pataki ni gele, ode pataki si ni wọn maa n we e lọ.  

Ẹ pade wa ninu apa keji apilẹkọ yii, nibi ta o ti maa sọrọ lori oriṣii gele to wa, bi wọn ṣe n we e, ati iyatọ gele wiwe laye atijọ si ti ode oni. 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search