Owe kan nilẹ Yoruba sọ pe: Iku ogun ni i pa akikanju, iku odo ni i pa omuwẹ, iku ẹwa, ni i pa ọkin, iku ara rire ni i pa oodẹ. Ẹyẹ odidẹrẹ, ti wọn tun n pe ni oodẹ fẹran lati maa re’ra, tabi lede mi-in, o n ṣe oge. Bakan naa, agba-ọjẹ onifuji nni, King Wasiu Ayinde, tawọn eeyan mọ si Kwam 1 kọrin ninu awo rẹ kan pe: Oge ṣiṣe ti daye ọna ti jin o Ka trending ti daye ọjọ ti pẹ Bi wọn ti mi ṣ’oge, bẹẹ la mi ṣ’oge Awa ko ni i f’oge silẹ ka ma ṣe, Gasikiya, orin naa lo b’oge lọ.
Owe ati orin yii fihan pe pataki ni ọrọ oge ṣiṣe jẹ nilẹ Yoruba, bo ṣe han ninu ọrọ, orin, owe, aṣamọ ati eebu wọn, bẹẹ lọrọ oge ṣiṣe ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ninu aṣa ilẹ adulawọ.
Ọrọ orukọ ti Yoruba maa n pe wundia, iyẹn ọdọmọbinrin to ti balaga, amọ ti ko tii wọle ọkọ ni ‘ọmọge’. Apetan ọrọ yii tumọ si ọlọmu oge, eyi to n tẹnu mọ irisi, ẹwa ati ayẹsi irufẹ ọmọbinrin bẹẹ.
Oriṣiiriṣii ọna ni Yoruba gbe oge ṣiṣe gba, bẹẹ ni wọn ni ọkan-o-jọkan nnkan eelo iṣaraloge. Oge ṣiṣe bẹrẹ latori irun didi fun obinrin, bii ki wọn di ṣuku, kọjusọkọ, kẹyinsale, ipakọ ẹlẹdẹ, tẹwọgbowo ati bẹẹ bẹẹ lọ, tabi irun gigẹ, fifa ori kodoro fun ọkunrin. Aṣọ wiwọ, dida bira si aṣọ loriṣiiriṣii ọna, fifi aro ṣe ọnà sara aṣọ wa lara oge ṣiṣe. Bẹẹ ni ṣiṣe ara lọṣọọ, bii keeyan tọ laali si ọwọ tabi ẹsẹ, kikun osun, ara finfin, eyi tọ jọra pẹlu aṣa yiya tatuu (tatoo) sara lode oni naa wa nibẹ pẹlu.
Lara iṣaraloge ni lilu eti, lilu imu, wiwọ yẹri eti, tabi yẹti, lilo ilẹkẹ ọrun, tabi wiwọ ilẹkẹ sibadi tabi idi, ẹgba ọrun tabi ti ẹsẹ. Laye ọjọun, awọn obinrin tun maa n di bebe sidii wọn lati le mu ki wọn dun-un-wo, ki wọn le maa da ọkunrin lọrun, ki wọn si di arimaleelọ.
Oge ṣiṣẹ ko duro sori imura tabi iṣaraloge nikan, o tun maa n han ninu irinsẹ ati ijokoo nigba mi-in, eyi le mu ki wọn sọ pe ẹnikan n rin irin oge, tabi pe onitọhun n ṣakọ.
Ni aye ode oni ti a ba ri ẹni ti o kọ ila, awon ọdọ ati awọn akẹgbẹ rẹ le bẹrẹ si fi i ṣe yẹyẹ nitori pe wọn ri ila kikọ gẹgẹ bii aṣa aye atijọ ti ko yẹ ki a maa ri ni ode-oni mọ. Bẹẹ yatọ si pe ila kikọ jẹ aṣa to n fi ilu, agbegbe ati idile ti ẹnikan ti wa han laye ọjọun, o tun jẹ oriṣii ọna oge ṣiṣe pẹlu.
Gẹgẹ bii Wasiu Ayinde ṣe sọ, titi di oni ni oge ṣiṣe n gbooro, to si n gba ọna igbalode pẹlu. Koda awọn eeyan n lo imọ ẹrọ lati ṣe oge, oge ṣiṣe si ti di ọna okoowo laarin tọkunrin tobinrin lori ẹrọ ayelujara, eyi lo fa a ti awọn kan fi n ṣiṣẹ afẹwa-pa’wo tawọn eleebo n pe ni modelling, bẹẹ lawọn mi-in n ṣiṣẹ fifi oge ko ero jọ, eyi ti wọn n pe ni social influencer.
Imọ ẹrọ ti mu ko ṣee ṣe fawọn eeyan kan lati pa irisi abinibi wọn da, ọkunrin le lo imọ ijinlẹ lati yi irisi rẹ pada si ti ọkunrin, bẹẹ l’obinrin naa si le bẹrẹ si i ṣe bii ọkunrin ni irisi, oriṣii oge igbalode kan ni, o si ti n ṣẹlẹ laarin ilẹ Yoruba naa, bo tilẹ jẹ pe ko wọpọ.
Ẹ tẹle wa lori ikanni ITAFAAJI bi a o ṣe maa ṣe atupalẹ awọn oniruuru ọnà oge ṣiṣe nilẹ Yoruba.