Itafaaji

Akara: Ounjẹ abalaye, ipanu aladun, ajẹpọnnula

Yoruba bọ, wọn ni ‘waa gba akara, waa gba du-n-du, lọmọde fi n mọ oju eeyan daadaa’. Akara jẹ ọkan ninu awọn ounjẹ ilẹ wa ti tọmọde-tagba fẹran gidi, nitori ounjẹ adidun to ṣee jẹ bii ipanu tabi ipapanu ni, bẹẹ leeyan tun le jẹ ẹ yo bamu.

Ipanu tabi ipapanu ni oriṣii nnkan jijẹ ti Yoruba ka si kẹnu-ma-dilẹ. O le jẹ ounjẹ keekeekee teeyan le jẹ lati mu inu ro, ti yoo din ebi ku, titi di igba ti ounjẹ gidi yoo ṣẹlẹ. Nigba mi-in si ree, ipanu le waye lẹyin ounjẹ gidi, boya nitori nnkan ipanu naa jẹ eyi teeyan fẹran lati jẹ, ko si ni i ṣepalara fun ara. Lara awọn nnkan ipanu bẹẹ ni guguru, ẹpa, akara, ọjọjọ, kokoro, bọọli ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Amọ ni ti akara, nitori ẹwa ni wọn fi n ṣe e, eeyan le jẹ ẹ yo, ti yoo dipo ounjẹ gidi, o si tun lọ papọ pẹlu awọn ounjẹ mi-in bii burẹdi, ẹkọ ati gaari. Ohun to tun mu ki ọpọ eeyan fẹran akara ni pe ko ṣoro lati ṣe. Laarin akoko perete, bi iṣu ṣe le parada ko di iyan, bẹẹ ni ẹwa yoo parada di akara.

Bawo ni wọn ṣe n ṣe akara?
Awọn eroja ati irinṣẹ teeyan nilo lati ṣe akara ni ẹwa, iyọ, epo tabi ororo, ata, alubọsa, ọlọ, ati iṣasun. A o rẹ ẹwa si omi fun iṣẹju diẹ, a o si fi ọwọ gbo o lati bo eepo ẹwa naa kuro. A le fi asẹ yọ eepo ọhun danu, titi ti yoo fi ku ekida ẹwa ti ko leepo lara. Lẹyin eyi, ẹwa naa yoo di lilọ lori ọlọ. Amọ lode iwoyi, a le lọọ pẹlu ẹrọ ilọta, titi ti yoo fi kunna. A le lọ ata ati alubọsa mọ ọn, a si le fọwọ rẹ alubọsa ati ata rodo naa si wẹwẹ, a o po o pọ pẹlu odiwọn iyọ to yẹ.

A o bẹrẹ si i fi ṣibi bu ẹwa lilọ naa sinu ororo tabi epo gigbona lori ina, a o si fi silẹ titi ti ẹwa funfun naa yoo fi pọn rẹsurẹsu, a le lo ṣibi tabi iwakara, tabi igi tẹẹrẹ yi ẹgbẹ keji akara naa pada, ko le jinna dọgba. A o wa a kuro ninu ororo tabi epo naa, ounjẹ adidun ti delẹ niyẹn.

Yooba ni bọmọde royin aa sọ akara nu, eyi fihan pe akara dun o si ṣara loore, ajẹpọnnula bii oyin ni.

Eeyan si tun le mu akara bii okoowo, tori nilẹ Yoruba, ọpọ eeyan fẹran lati jẹ ẹ laarọ ati laṣalẹ, agaga pẹlu ẹkọ gbigbona tabi ori. Obinrin to n di akara ta ni wọn maa n pe ni Iya alakara nilẹ Yoruba, o si ti di owo aṣela aṣelokiki fawọn mi-in.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search