Itafaaji

Ẹniọla Badmus binu fesi fawọn to ni aye ẹ maa ri bii aye Naijiria

Yoruba bọ, wọn ni ‘isọrọ-nigbesi, isunmusi nigbete-gan-n-gan. Ọrọ yii lo wọ bi gbajugbaja oṣere-binrin onitiata ilẹ wa to lomi lara daadaa nni, Ẹniọla Badmus, tawọn eeyan tun mọ si Wule Bantu, ṣe fibinu fesi pada fun ọpọ lara awọn ololufẹ rẹ lori ẹrọ ayelujara, bi wọn ṣe juko ọrọ buruku si obinrin naa loun naa fesi ọrọ kobakungbe pada si wọn, n l’ọrọ ba di ‘oko ta a sọ mọ ọpẹ l’ọpẹ n sọ mọni’ laaarin wọn.

Ohun to ya awọn eeyan lẹnu lori ọrọ ọhun ni pe ayajọ ọdun ominira orileede Naijiria ti pọpọṣinṣin rẹ ṣi n lọ lọwọ lọrọ naa waye, ọjọ to yẹ kawọn eeyan maa yọ, ki wọn si maa ki ara wọn kuu oriire ni, boya eyi ni Ẹniọla Badmus ni lọkan to fi kọ ọrọ ikinu kuu oriire kan soju opo Instagiraamu rẹ lọjọ naa, iyẹn ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii, amọ ohun to reti kọ lo ba pade.

Ẹniọla lo kọkọ fi idunnu rẹ han lọjọ naa, pẹlu bo ṣe gba ori ikanni rẹ lọ, o gbe awọn fọto rirẹwa kan to diidi ya lati fi ṣeranti ati ayẹyẹ ọjọ ominira Naijiria sibẹ, nitori yatọ si ti aṣọ alawọ funfun ati alawọ ewe to wọ, eyi to ṣe rẹgi pẹlu awọ asia orileede Naijiria, awọn fọto naa rẹwa, o si joju ni gbese, koda eeyan fẹrẹ ma le mọ pe Ẹniọla Badmus ni wọn ya sibẹ. Obinrin to lomi lara, to ri rumurumu, ti ọjọ iwaju rẹ kun, ti akọyinsi rẹ naa ko si kẹrẹ lawọn eeyan mọ oṣere-binrin yii si latilẹ, amọ ninu fọto naa, o ti di obinrin ti isanra rẹ ti din ku jọjọ, to si tubọ rẹwa si i.

Labẹ fọto yii lo kọ ọrọ si pe kawọn ololufẹ oun dara pọ mọ oun lati ṣayẹyẹ ominira Naijiria, o ni:

“Oni yii la n sami ọdun mi-in ti orileede Naijiria gba ominira, iṣọkan ati idagbasoke. Ọjọ yii la maa n ranti okun ati aikaarẹ awọn eeyan rẹ, ọkan-o-jọkan aṣa rẹpẹtẹ to nitumọ, ati awọn igbesẹ akin ta a gbe lati bori awọn ipenija wa latigba ta a ti gbominira lọdun 1960.

“A kuu ayọ ọjọ kinni oṣu Kẹwaa, a kuu ajọyọ ayajọ ominira o, Naijiria. Ẹ jẹ ka ṣayẹyẹ asia olomi ewe ati funfun wa, ka si yangan pẹlu rẹ.”

O daju pe ọrọ ti Ẹniọla Badmus kọ yii ko dun mọ awọn eeyan ninu rara. Nigba tawọn ololufẹ rẹ kan ṣe ariwisi nipa fọto rẹ, ti wọn fẹsun kan an pe niṣe lo lo ẹrọ lati dọgbọn si fọto naa ki irisi rẹ le dun-un-wo, ọrọ ti bo ṣe jẹ alatilẹyin fun ijọba to wa lode yii lo bi awọn kan ninu, wọn ni oṣere naa ko tiẹ ro ti ipọnju ati inira tawọn eeyan n ba finra, ko too maa sọrọ.

Ẹnikan ti ọrọ rẹ ka Ẹniọla lara ju lo sọ pe: “Aye ẹ maa dabi aye Naijiria. Ọlọrun maa jẹ ki aye ẹ sare di yẹpẹrẹ bii owo Naira too sọ pe o ti n lagbara si i yii ni. Ọlọrun maa jẹ ko o wa nipo ti Naijiria wa yii ni. Ṣe amin to rinlẹ ki n gbọ!”

O jọ pe ọrọ yii bi Ẹniọla ninu gidigidi, tori niṣe loun naa fesi pada fun onitọhun pe: “Bẹẹ lo maa ri fun iwọ ati gbogbo mọlẹbi ẹ patapata, titi kan awọn ọmọ ẹ too tii bi pẹlu.”

Onitọhun naa tun fesi pada si Ẹniọla pe: “O ma ga o, ki lo de tẹẹ wa n da a pada, Ma? Ṣebi ẹ sọ pe nnkan n lọ daadaa fun Naijiria ni? Ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ẹnikan tun sọ fun Ẹniọla pe: “Niṣe ni ko o ṣe Amin si adura yẹn, ko o si maa ba tiẹ lọ o.”

 

 

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search