Orin wo ni ka kọ si gbẹdu lọrọ di nigba ti esuro padida to n le aja laarin alakooso ere bọọlu alafẹsẹgba lori papa, eyi tawọn eleebo n pe ni rẹfiri, Fabio Maresca, nigba ti wọn fẹsun kan ọkunrin to yẹ ko maa pẹtu saawọ lori papa yii pe oun gan-an lo gbe ibinu wọ, wọn lo leri, o si taka si agbabọọlu kan pe ọjọ toun ba tun pade ẹ, oun maa pa a ni. Eyi lo mu kawọn alaṣẹ bọọlu alafẹsẹgba liigi EUFA Champions League jawee gbele ẹ fun un.
Ọrọ kan ti ileeṣẹ agberoyinjade Corriere della Sera via Football Italia gbe jade, eyi to tẹ ITAFAAJI lọwọ fihan pe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an ọdun 2024 yii niṣẹlẹ naa waye, lasiko ifẹsẹwọnsẹ laaarin ẹgbẹ agbabọọlu Kuwait SC ati Al-Arabi.
Wọn ni lọjọ Tusidee, ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa yii ni agbabọọlu ti rẹfiri dunkooko mọ ọhun mu ẹjọ rẹ lọọ ọdọ awọn alakooso ere idaraya naa. Ninu ẹsun ọhun, wọn ni rẹfiri yii sọ fun agbabọọlu to binu si naa pe:”Emi atiẹ maa ṣi maa pade, maa pa ẹ ni”, bo tilẹ jẹ pe awọn mi-in n sọ pe agbabeej