Itafaaji

O ma ṣe o! Awọn oṣere tiata ṣedaro ọmọ Saidi Balogun to ku lojiji

Titi dasiko ta a wa yii ni ọrọ ibanikẹdun ati aro ṣi n rọ wọle sori ikanni gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa nni, Saidi Balogun, latari iku ọmọ rẹ obinrin, Zeenat Gbemisọla Balogun, to jade laye lairoti, lopin ọsẹ to kọja yii.

Ọjọ ibanujẹ gbaa ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karun-un, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii ja si fun eekan oṣere tiata to tun maa n gbe fiimu jade nni, Saidi, tori Yoruba bọ, wọn ni ibanujẹ nla ki majeṣin toju obi rẹ ku, oun lo si n mu ki wọn ṣadura nigba mi-in pe ‘ki ẹlẹyin maṣe ṣiwaju, k’oniwaju maṣe kẹyin,’ bo tilẹ jẹ pe ọrọ iku kọja bẹẹ.

Ko sẹni to tii mọ hulẹ-hulẹ ohun to ṣokunfa iku ojiji ọhun, ati bi iṣẹlẹ naa ṣe waye gan-an, amọ ninu fọto kan to hande lori ẹrọ ayelujara, o ṣe kedere pe Saidi Balogun nifẹẹ ọmọbinrin rẹ yii nigba to wa laye, ọmọ naa jọ ọ bii imumu, bi baba rẹ ṣe pupa loun naa pọn bii ọlẹlẹ, baba atọmọ naa si gbori le ara wọn, pẹlu ẹrin ati idunnu loju wọn, ninu fọto naa.

Saidi Balogun, ọkọ ilumọ-ọn-ka onitiata to rẹwa daadaa nni, Fathia Balogun, ki ija to de, ti orin si dowe laarin wọn lọdun diẹ sẹyin, lo gbe aworan kan soju opo instagiraamu rẹ lọjọ Satide ọhun, lati tufọ iku ọmọbinrin rẹ yii. Fọto dudu kan ni, pẹlu abẹla ti ina rẹ ti ku, to wa laarin ododo, eyi si jẹ aroko igbalode lati fihan pe ọfọ nla ti ṣẹ.

Lẹyẹ-o-sọka lawọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ, atawọn ololufẹ eekan oṣere naa, titi kan awọn onigbọwọ ere tiata atawọn oloṣelu kọọkan ti n kọ ọrọ ibanikẹdun nipa iṣẹlẹ ọhun, ti wọn n ki Saidi Balogun pe ko mọkanle, ko ṣe bii ọkunrin, bẹẹ ni wọn n ṣadura fun un pe Ọlọrun yoo tu u ninu, yoo rẹ ẹ lẹkun, yoo si dawọ ibi duro lori idile rẹ.

Oṣere tiata kan, Allwell Ademọla ni: “Mi o mọ ọrọ ti mo le sọ o. Afi ki eleyii jẹ ala lasan o. Ọlọrun o, Osenatu mi!”  Oluwaṣeyi Ẹdun, toun naa fẹ onitiata ẹlẹgbẹ rẹ ni: “Mo ba yin daro Sa, ki Ọlọrun tun idile yin ninu o.”

Adeniyi Johnson, ọkọ Ṣeyi Ẹdun ni: “Mo ṣedaro pẹlu yin Sa.” Agba oṣere-binrin nni, Ọlajumọkẹ Ọlatunde George ni: “Ọlọrun mi o, eyi lagbara o. Mo ṣedaro pẹlu yin o, arakunrin mi ọwọn. Ki Allah fun ọkan rẹ ni isinmi o”.

Ni ti Ronkẹ Odusanya, o ni: “Ẹ jọwọ, ẹ mọkanle Sa, o ti daa.”           
Bakan naa ni awọn gbajumọ oṣere tiata bii Abilekọ Abiọdun Ṣofuyi ti wọn n pe ni Ọmọborty, Lateef Adedimeji, Dayọ Amusa, Ọmọwunmi Ajiboye, iyẹn iyawo Ṣẹgun Ogungbe toun naa jẹ eekan onitiata, Yọmi Faṣh Lanṣo, Kunle Afod, Fausat Balogun, ti wọn n pe ni Madam Ṣajẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ṣedaro Gbemisọla Zeenat, ọmọ Saidi Balogun, to ku.

Titi dasiko ta a wa yii ni ọrọ ibanikẹdun ati aro ṣi n rọ wọle sori ikanni gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa nni, Saidi Balogun, latari iku ọmọ rẹ obinrin, Zeenat Gbemisọla Balogun, to jade laye lairoti, lopin ọsẹ to kọja yii.

Ọjọ ibanujẹ gbaa ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karun-un, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii ja si fun eekan oṣere tiata to tun maa n gbe fiimu jade nni, Saidi, tori Yoruba bọ, wọn ni ibanujẹ nla ki majeṣin toju obi rẹ ku, oun lo si n mu ki wọn ṣadura nigba mi-in pe ‘ki ẹlẹyin maṣe ṣiwaju, k’oniwaju maṣe kẹyin,’ bo tilẹ jẹ pe ọrọ iku kọja bẹẹ.

Ko sẹni to tii mọ hulẹ-hulẹ ohun to ṣokunfa iku ojiji ọhun, ati bi iṣẹlẹ naa waye gan-an, amọ ninu fọto kan to hande lori ẹrọ ayelujara, o ṣe kedere pe Saidi Balogun nifẹẹ ọmọbinrin rẹ yii nigba to wa laye, ọmọ naa jọ ọ bii imumu, bi baba rẹ ṣe pupa loun naa pọn bii ọlẹlẹ, baba atọmọ naa si gbori le ara wọn, pẹlu ẹrin ati idunnu loju wọn, ninu fọto naa.

Saidi Balogun, ọkọ ilumọ-ọn-ka onitiata to rẹwa daadaa nni, Fathia Balogun, ki ija to de, ti orin si d’owe laarin wọn lọdun diẹ sẹyin, lo gbe aworan kan soju opo instagiraamu rẹ lọjọ Satide ọhun, lati tufọ iku ọmọbinrin rẹ yii. Fọto dudu kan ni, pẹlu abẹla ti ina rẹ ti ku, to wa laarin ododo, eyi si jẹ aroko igbalode lati fihan pe ọfọ nla ti ṣẹ.

Lẹyẹ-o-sọka lawọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ, atawọn ololufẹ eekan oṣere naa, titi kan awọn onigbọwọ ere tiata atawọn oloṣelu kọọkan ti n kọ ọrọ ibanikẹdun nipa iṣẹlẹ ọhun, ti wọn n ki Saidi Balogun pe ko mọkanle, ko ṣe bii ọkunrin, bẹẹ ni wọn n ṣadura fun un pe Ọlọrun yoo tu u ninu, yoo rẹ ẹ lẹkun, yoo si dawọ ibi duro lori idile rẹ.

Oṣere tiata kan, Allwell Ademọla ni: “Mi o mọ ọrọ ti mo le sọ o. Afi ki eleyii jẹ ala lasan o. Ọlọrun o, Osenatu mi!”

Oluwaṣeyi Ẹdun, toun naa fẹ onitiata ẹlẹgbẹ rẹ ni: “Mo ba yin daro Sa, ki Ọlọrun tun idile yin ninu o.” Adeniyi Johnson, ọkọ Ṣeyi Ẹdun ni: “Mo ṣedaro pẹlu yin Sa.”
Agba oṣere-binrin nni, Ọlajumọkẹ Ọlatunde George ni: “Ọlọrun mi o, eyi lagbara o. Mo ṣedaro pẹlu yin o, arakunrin mi ọwọn. Ki Allah fun ọkan rẹ ni isinmi o”.

Ni ti Ronkẹ Odusanya, o ni: “Ẹ jọwọ, ẹ mọkanle Sa, o ti daa.”  Bakan naa ni awọn gbajumọ oṣere tiata bii Abilekọ Abiọdun Ṣofuyi ti wọn n pe ni Ọmọborty, Lateef Adedimeji, Dayọ Amusa, Ọmọwunmi Ajiboye, iyẹn iyawo Ṣẹgun Ogungbe toun naa jẹ eekan onitiata, Yọmi Faṣh Lanṣo, Kunle Afod, Fausat Balogun, ti wọn n pe ni Madam Ṣajẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ṣedaro Gbemisọla Zeenat, ọmọ Saidi Balogun, to ku.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search