Gbogbo ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ninu ọdun ni baba agbalagba naa maa n ṣ’ọjọọbi rẹ, eyi lawọn ọrẹ rẹ kan fi maa n pe ni ọmọ ten-ten lede oyinbo, ayẹyẹ ti ọdun 2024 yii lo ṣi sọ Aluwẹẹ d’ẹni aadọrin ọdun.
Ninu ọrọ ikini kuu oriire ti Purẹsidẹnti Tinubu kọ si Aluwẹẹ, o ni: “Gbogbo ayọ ati idunnu ọjọ-ibi yii lo tọ si ọ. O ti ṣe ohun to mu ki inu ọpọ eeyan dun sí ọ jọjọ lati aadọrin ọdun yii wa. Tori ẹ, o ti to asiko fun ẹ lati gbadun awọn ọrọ apọnle ati idaniyan to dara ju lọ lat’ọdọ awọn ololufẹ rẹ. Ẹ kuu ajọyọ ọjọọbi aadọrin ọdun o!” Tinubu lo ki Aluwẹẹ bẹẹ.
Ẹnikan ti inu rẹ tun dun daadaa si Aluwẹẹ ni ọmọ rẹ ọkunrin, Ọgbẹni Ọlasunkanmi Ọmọbọlanle, niṣe lo gbe fọto kan nibi ti baba rẹ ti n yayọ lagbo ariya si i, pẹlu awo oju rẹ to fi okun so si igbaaya gẹgẹ bii àṣà baba naa ninu fiimu, o si kọ ọrọ iwuri sabẹ fọto naa, o ni: “Ẹ kuu ayẹyẹ ọjọ-ibi aadọrin ọdun o Baba mi, baba temi gan-an. Ki ẹ pẹ fun mi laṣẹ Edumare. Mo nifẹẹ yin Dadi mi”, o si gbe ami ifẹ sabẹ ọrọ naa.
Yẹmi Solade, toun naa jẹ eekan onitiata kọ ọrọ tiẹ pe: “Oloye Sunday Ọmọbọlanle, ti wọn mọ kaakiri agbaye si Papy Luwẹ tabi Aluwẹ, ọkan ninu àwọn oṣere ati alawada ilẹ Africa to lẹbun ju lọ… oṣere ti irawọ rẹ si n ran bii oorun ti dẹni aadọrin ọdun o. Mo ki yin kuu oriire.
Adebayọ Salami, t’awọn eeyan mọ sí Ọga Bello, naa ki Aluwẹẹ, o ni: “Mo ki agba-ọjẹ onitiata to fakọyọ laye kuu ayọ ọjọ-ibi ti aadọrin ọdun yii o. Ẹ kaabọ si awujọ awọn agbaagba ti wọn ti pe aadọrin ọdun l’oke eepẹ. Mo ba yin yọ o, Arakunrin mi”.
Ẹ o ranti pe lati kekere ni Aluwẹ ati Oga Bello ti jumọ n ṣe ere itage bọ, lati asiko ti wọn fi wa lẹyin Baba Mero laye ọjọun, ọpọ ọdun sí ni wọn fi ṣere papọ titi d’oni.
Aka-i-ka-tan lawọn oṣere to ki Aluwẹ kuu ayẹyẹ ọjọ-ibi rẹ yii. Lara wọn ni Abilekọ Ṣọla Ṣobọwale, Fausat Balogun ti inagijẹ rẹ n jẹ Madam Sajẹ, Mama Lanre Hassan ti ọpọ mọ si Iya Awẹro, Ọpẹyẹmi Aiyeọla, Dayọ Amusa, Jumọkẹ George, Kevin Ikeduba, Toyọsi Adesanya, Tọpẹ Adebayọ Salami, Funkẹ Etti, Jide Awobọna ati bẹẹ bẹẹ lọ.
ITAFAAJI yoo mu ẹkunrẹrẹ itan igbesi aye aderin-in poṣonu yii wa fun igbadun ẹyin ololufẹ wa laipẹ. Ẹ kuu oju lọna.