Itafaaji

Eyi lamọran Laide Bakare f’awọn ọmọge asiko

Pẹlu bi ọpọlọpọ awon ọlọmọge ati awọn obinrin ṣe n lakaka lati di ilumọ-ọn-ka ati irawọ nidii iṣẹ aje ati okoowo ti wọn yan laayo lasiko yii, gbajugbaja oṣere tiata, toun tun ti di ipo oṣelu mu bayii, Laide Bakare, ti fi ọrọ amọran lede to fẹ ki wọn samulo rẹ.

Laide ni amọran oun fun wọn ni pe ki awọn irufẹ awọn obinrin bẹẹ tete wọle ọkọ, ki wọn tete ṣe igbeyawo, ki wọn le bi ọmọ ti wọn ba fẹẹ bi, ki wọn si tọ wọn, ki wọn le r’oju raaye gbaju mọ iṣẹ ti wọn fẹẹ fi aye wọn ṣe.

Lasiko to n dahun ibeere ninu eto ori redio kan lori ẹrọ ayelujara laipẹ yii ni Laide sọrọ ọhun. Oserebirin to rẹwa daadaa nni, Laide, sọ pe: “To o ba fẹẹ di irawọ oṣere, to o fẹẹ ṣaṣeyọri nidii iṣẹ to o yan lati fi aye ẹ ṣe gẹgẹ bii ọdọmọbinrin, maa gba yin lamọran pe kẹẹ tete ṣe igbeyawo kẹẹ dẹ tete bi ọmọ tẹẹ ba fẹẹ bi.

“Eyi maa jẹ ko rọrun fun yin lati ribi lo iyoku aye yin nidii iṣẹ tẹẹ yan laayo, nitori ọrọ idile ṣe pataki.” Ṣe Yooba bọ, wọn ni iriri ṣ’agba ọgbọn, bi ko ba ṣi ṣe’ni ri, a kii pe o tun de si’ni, obinrin to ti wa ni ipo Oludamọran Pataki si Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke bayii fikun ọrọ rẹ pe:

“Boya ki n tun ọrọ mi sọ tori ki I ṣe igbeyawo gan-an ni mo ni l’ọkan, amọ awọn obinrin ti wọn n ronu igbeyawo ti wọn ṣi fẹẹ pa a pọ mọ iṣẹ wọn ni mo n sọ. Emi o ronu igbeyawo rara ati rara nigba temi. Lasiko ti mo bimọ akọbi mi, ọmọ lo kan wu mi nigba yẹn.”

Laide ni k’awọn olugbọ oun ma ṣi oun gbọ o. O loun o sọrọ nipa igbeyawo o, ọrọ bi wọn ṣe maa ni idile tiwọn paapaapaa ki wọn le gbaju mọ iṣẹ loun n ba wọn sọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search