Ọpọ awọn ololufẹ oṣere tiata mejeeji yii ni ọrọ naa ṣi n ya lẹnu, nitori pe inu okunkun ni wọn wa, ọpọ lo si n mefo, ti wọn n haragaga lati mọ pato ohun ti awọn fẹẹ maa dupẹ oloore le lori, o ṣetan ọpẹ oloore, adu-i-du-tan ni, bi Yoruba ṣe maa n wi.
Adeniyi Johnson, ilumọ-ọn-ka oṣere tiata, to jẹ ọkọ oṣere-binrin nni, Ṣeyi Ẹdun, lo gba ori ikanni Instagiraamu rẹ lọ l’ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii, lo ba gbe ọrọ kan sibẹ, boun alara ṣe n dupẹ lọwọ gbajumọ oṣere tiata to rẹwa bii egbin nni, Mercy Aigbe, bẹẹ lo tun n dupẹ lọwọ ọkọ to rẹ, Alaaji Kazim Adeoti, fun oore pataki kan to ni wọn ṣe oun lọjọ naa, bẹẹ lo parọwa fawọn ololufẹ rẹ, o ni:
“Ẹ ṣeun lọpọlọpọ fun nnkan tẹẹ ṣe fun mi loni-in Sa ati Ma. Mo dupẹ, dupẹ o.
“Ẹyin ọrẹ ati mọlẹbi mi, ẹ ba mi ṣadura fun Mercy Aigbe kẹẹ si dupẹ lọwọ wọn o.” Lo ba gbe ami ifẹ meji sabẹ ọrọ naa.
Ọpọ awọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ wọn ni wọn dahun si ọrọ Adeniyi yii, ti wọn gboṣuba fun Mercy Aigbe ati ọkọ rẹ, bẹẹ ni wọn fi ami ifẹ han si Adeniyi.
Tẹẹ o ba gbagbe, Adeniyi dupẹ gidigidi lọwọ Mercy Aigbe lọdun to kọja nigba ti iyawo rẹ bi ibeji lanti-lanti, ti wọn si fi ọpọ ẹbun olowo iyebiye ta wọn lọrẹ
Baba Ẹdunjọbi yii ṣalaye pe ọpẹlọpẹ Mercy Aigbe laye oun, oun lo foju oun m’ọna iṣẹ tiata, oun lo si fa ọwọ oun goke nidii iṣẹ naa
Ṣe ‘bu-fun-mi ki-n-bu-fun-ọ’ l’ọpọlọ n ke lodo, Mercy naa kọ ọrọ imọriri kan si Adeniyi Johnson lẹnu aipẹ yii, nibi to ti ṣapejuwe Baba Ibeji yii bii ẹda to ṣee f’ọkan tẹ, to ṣee gbara le, ati pe o ṣe atilẹyin gidi fun oun nidii iṣẹ toun n ṣe.