Ọrọ to n ja ranyin bii ina ọyẹ́, to n jó fofo bii ẹwiri alagbedẹ lasiko yii ni ti ẹsun ti wọn fi kan Ọmọwumi, tabi Wumi, tii ṣe iyawo gbajumọ oṣere hip-hop ti iku rẹ da awuyewuye silẹ lori ayelujara nni, Oloogbe Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, ti ọpọ eeyan mọ si Mohbad, wọn lọmọbinrin naa ti fẹraku, o ti loyun.
Bi ọrọ yii ṣe n ṣe ọpọ awọn to gbọ nipa rẹ ni haa-hin, ti wọn n lanu ti wọn ko si le pa a de, t’awọn mi-in si ni n fọwọ lu’wọ pe ko jẹ jẹ bẹẹ, bẹẹ lawọn kan n jo ‘jàgínní-yòdò’, ti wọn n ṣe ‘ko-ha-tan-bi?’ awọn ti wí bẹẹ tẹlẹ pe aṣiri alabosi ko nii pẹ tu, sibẹ epe lawọn kan n gbe Wumi ṣẹ, wọn ni tọrọ naa ba fi le jẹ ootọ, obinrin yii ti ba awọn loju jẹ niyẹn, eebu ati epe lawọn si maa ma a fi ranṣẹ si i.
Lori ikanni TikTok kan ti wọn n pe ni Baba Latisneh lori ẹrọ ayelujara lọrọ naa ti bẹrẹ, ibẹ leefin rẹ ti kọkọ ru tuu lopin lopin ọsẹ to kọja yii, lasiko ti ijiroro waye lori ibi ti nnkan de duro l’ori ọrọ Mohbad, ibẹ lawọn kan ti wọn lawọn mọ bo ṣe n lọ ti ju bọmbu ọrọ, wọn ni Wumi ti loyun, ẹlomi-in ti fun un loyun.
Bo tilẹ jẹ pe oludari eto naa ja fitafita pe k’awọn to fẹẹ gba ọrọ ọhun bii ẹni gba’gba ọti ṣi mu suuru na, ki wọn jẹ k’oun lọọ ṣewadii lati fifi ododo mulẹ na, amọ ẹyin lohùn, bo ba ti jabọ ko ṣe ṣa, niṣe lọrọ naa da awuyewuye silẹ, ko sẹni to fún ẹnìkejì lọrọ sọ, kaluku lo n sọ tirẹ.
Titi dasiko yii, ITAFAAJI ko tii le fidi ọrọ naa mulẹ, amọ o jọ pe atẹgun ọrọ naa ti fẹ de ọdọ ẹni tọrọ ọhun kan gbọngbọn, iyẹn Wumi, iyawo Mohbad, pẹlu bi ti ṣe gba ori ikanni Instagiraamu rẹ lọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii, to si paroko ọrọ kan sibẹ lati fesi si rumọọsi buruku ọhun. Wumi ko sọ pato kan o, lowe-lowe la a lu ilu agidigbo lo fi i ṣe, ṣoki lo si kọ ọrọ rẹ, o ni:
“Bi igbesi aye mi ba ṣe ri si mi lohun to jẹ emi logun ni t’emi o, bo ṣe ri s’awọn mi-in ko kan mi.”
Ni bayii, pẹlu ohun ti Wumi so yii, awọn kan ti n gbeja rẹ pe ki wọn fi ọmọbinrin naa lọrun silẹ ko gbadun aye ẹ bo ṣe wù u, wọn ni ko le maa ṣe opo titi aye, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe to ba fi jẹ loootọ lo ti di abarameji laarin ọdun kan iku ọkọ rẹ, ti awuyewuye iku MohBad ko si tii tan nilẹ, ti Liam, ọmọ-ọwọ rẹ si ṣi kere, wọn lo ku-diẹ-ka-a-to, tori ohun ti ko dara ko lorukọ meji.
Ọrọ to n ja ranyin bii ina ọyẹ́, to n jó fofo bii ẹwiri alagbedẹ lasiko yii ni ti ẹsun ti wọn fi kan Ọmọwumi, tabi Wumi, tii ṣe iyawo gbajumọ oṣere hip-hop ti iku rẹ da awuyewuye silẹ lori ayelujara nni, Oloogbe Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, ti ọpọ eeyan mọ si Mohbad, wọn lọmọbinrin naa ti fẹraku, o ti loyun.