Ọkan pataki ninu awọn agbatẹru ati igi lẹyin ọgbà ileeṣẹ Quantum Valley Limited to fikalẹ s’agbegbe Igbọkọda, nipinlẹ Ondo, ni Naijiria, Ọjọgbọn Ade Ọjẹniyi ti jade laye.
Bi ITAFAAJI ṣe fidi ẹ mulẹ, niṣe ni baba agbalagba to kẹkọọ-gboye Purofẹsọ nipa eto ilera ati itọju awọn ẹranko naa sun oorun asunwọra nile rẹ lọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii, amọ ko s’ẹni to fura pe ọlọjọ ti wa nitosi, afigba ti baba naa ju awa silẹ, ti ina si dilẹ lẹyin asunṣujẹ rẹ.
Latigba ti ọrọ nipa iku ẹni ọwọn yii ti gori afẹfẹ lawọn mọlẹbi, ololufẹ, ọrẹ ati ojulumọ ti n ṣedaro rẹ.
Ileeṣẹ Quantum Valley, labẹ idari Alagba Stephen King, ṣapejuwe Oloogbe yii gẹgẹ bíi ọkan lara ojulowo ọmọ Naijiria atata, to t’ayọ, to si jẹ ọmọluabi ni gbogbo ọna. Ọjọgbọn yii, ti wọn fi oye Knight of the Dannenbrog, lorileede Denmark da lọla lọjọ karun-un, oṣu Kinni, ọdun 2018, peregede o fi gbọrọ jẹ’ka ninu iran adulawọ.
ITAFAAJI yoo maa fi bi eto isinku ọkunrin takun-takun yii yoo ṣe lọ si ti yin leti