Tibi tire la da ile aye, b’awọn agba ṣe maa n sọ, ti wọn si maa n ṣadura pe ire inu rẹ lo dara ko kan’ni, ki Ọlọrun ba’ni re ibi siwaju ni, ati pe makan-makan loye n kan, iru ẹ ni ti ipo ti agba-ọjẹ onitiata ilẹ wa, to gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta nni, Ọmọọba Jide Kosọkọ wa bayii, pẹlu ipo agba, ipo olori ti wọn ṣẹṣẹ fi da a lọla ninu idile rẹ, o ti di Olori-ẹbi Ọtẹniya, ninu agboole Ọba Kosọkọ niluu Eko Akete, idile ọlọba!
Ṣe ẹnu ọlọfa la a tii gbọ ‘mo ta a’, Jide Kosọkọ fúnra rẹ lọ kede ọrọ ọhun faye gbọ lori ikanni Instagiraamu rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii.
O ṣalaye pe l’ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, oṣu Kẹwaa yii agbarijọpọ awọn baale baale at’awọn agbaagba ẹbi naa pe apero pataki lati fori ikooko ṣọọdun ni ti ẹni ti yoo bọ sipo Olori-ẹbi Ọtẹniya lagboole Kosọkọ ọhun, iyalẹnu lọ sì jẹ nigba ti wọn da ọrọ ọhun lọ, ti wọn da a bọ, ti wọn si panu-pọ yan oun sipo pataki naa.
Bayii ni Jide ṣe sọrọ ọhun, o ni: “Ni bayii o, lati asiko yii lọ, wọn ti fidi ẹ mulẹ pe emi ni Olori-ẹbi igun ti Ọtẹniya ninu agboole Ọloba Kosọkọ, ọjọ kejila oṣu Ọkitoba yii ni wọn fa mi kalẹ, ti wọn ṣi gba mi wọle lati dara pọ mọ igbimọ awọn Olori-ẹbi Kosọkọ.
“Wọn si tun ti fontẹ jan an pe emi ni Aṣoju ẹbi naa bayii.
“Mo gbadura pe ki Ọlọrun, ninu aanu Rẹ ti ko l’opin, ko fun mi l’ọgbọn ki n le ṣe ipa temi lati mu iṣọkan ati ilọsiwaju ba ẹbi wa.”
Ninu fidio iyansipo naa ti Ọmọọba Jide Kosọkọ gbe sori ikanni rẹ, aṣọ alawọ buluu kan pẹlu fila to ṣe rẹgi, to sí dọgba pẹlu fila t’awọn igbimọ Olori-ẹbi to wa nikalẹ de ni Olori-ẹbi tuntun yii wọ, bi atọkun eto naa sí ṣe kede iyansipo rẹ ni Jide Kosọkọ ti dide, o ṣi fila, o si dọbalẹ lati fi ẹmi imoore ati idunnu rẹ han.
Atọkun eto naa tun kede pe nnkan ẹni kìí di meji k’inu o bini ni tọrọ Ọmọọba Jide Kosọkọ lasiko yii, o ni yatọ sí ti aṣoju tabi Ambassador ẹbi Ọtẹniya ti wọn ṣẹṣẹ yan an si, o loun naa tun ni aṣoju ẹbi Ẹṣinlokun nile loko, n latẹwọ ba n rọ ni wàá wàá.
Ṣa, lọrọ kan, bẹẹ ba ri irukẹrẹ lọwọ Omfridoma, tẹẹ si tun ri ilẹkẹ lọrun Jide Babs, Olori-ẹbi lẹẹ n wo yẹn o!