Bakan naa ni Yoruba ni ọkan-o-jọkan akanlo-ede, àpólà ọrọ ati aṣa to fihan bi wọn ti fẹran ariya to, bi ikun ṣe fẹran ẹpa, ti ọbọ ko le fi ọgẹdẹ ṣere, bẹẹ ni ariya ṣiṣe nilẹ Yoruba ṣe ri. Lara akanlo ede ati ọrọ bẹẹ ni ‘ode ariya’, pati, owanbẹ, faaji, faaji famia, faaji-n-ṣan, ariya-o-lopin, mo-gbọ-mo-ya, inawo, ayẹyẹ, oninawo, ṣabọ-jọ, pọpọ-ṣinṣin, abolode-fẹ-ẹ-loju, aṣọ-ẹbi, ankoo, aṣọ ẹgbẹjọda, oo-wọ-ankara-oo-jẹ-sẹmo, agbo ere, nawo felere, lẹ owo melere loju ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Oriṣiiriṣii nnkan lo maa n ṣokunfa ariya nilẹ Yoruba, o si pọ diẹ. Lara ariya ni ikomọjade ti wọn tun n pe ni isọmọlorukọ, oku ṣiṣe, igbeyawo, idana, mọ-mi-n-mọ-ọ, iṣile, didawọọ ọkọ tuntun, ṣiṣi ileeṣẹ tabi okoowo tuntun, fifi ipilẹ ile lelẹ, oye jijẹ, ọba jijẹ, ikẹkọọ-yege, ajọdun, ajọdun isin, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Eyi lo fi jẹ pe bi ariya kekere ṣe wa, bẹẹ ni pati nla wa, ko si sigba ti ayẹyẹ ko le ṣẹlẹ nilẹ Yoruba, agaga lopin ọsẹ, iyẹn ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ Abamẹta, Satide titi kan ọjọ Aiku, Sannde. Koda awọn kan máa n daṣa, wọn si tun n ṣẹfẹ pe ‘Satide lẹbọ n ṣẹlẹ’, tabi ‘Ọjọ gbogbo bii ọdun ni’.