Ṣe bi ko ba nidii, ẹṣẹ ki i deede ṣẹ, bi Yoruba ti n sọ, ohun to ṣokunfa lọgbọ-lọgbọ to waye ọhun ko ṣẹyin bawọn alaṣẹ orileede Libya ṣe dari ọkọ ofurufu to ko ikọ Super Eagles lati papakọ ofurufu Aminu Kano, nipinlẹ Kano ti wọn ti gbera lọjọ kẹtala, oṣu yii gba ibomi-in, dipo ti ọkọ ofurufu naa yoo fi balẹ siluu Bengazhi ti wọn ti jọ fi adehun si tẹlẹ, papakọ ofurufu nla ti Al-Abraq ni wọn ja wọn si, fun ohun to ju wakati mẹrindinlogun lọ si ni awọn agbabọọlu at’awọn kooṣi wọn fi laalaṣi ninu iporuuru ọkan, wọn ko rẹni fun wọn ni ounjẹ ati omi, awọn olugbalejo wọn ko yọju ki wọn kaabọ, depo-depo ki wọn pese ilegbee fun wọn.
Ibinu iwa ilaalaṣi-ẹni lainidii ti wọn hu yii lo mu kijọba Naijiria paṣẹ fun ikọ Super Eagles lati pada sile lẹyẹ-o-sọka, wọn si kọwe lati fẹjọ Libya sun CAF, wọn sọ ohun ti wọn foju wọn kan.
Eyi lo mu ki ajọ CAF kọwe ‘waa-wi-tẹnu-ẹ’ si Libya, ki wọn sọ ohun ti wọn ri l’ọbẹ ti wọn fi waro ọwọ lori ẹsun ti Naijiria fi kan wọn ọhun.
Ọgbẹni Nasser Al-Suwaie, to jẹ akọwe agba ati alakooso ajọ bọọlu alafẹsẹgba ilẹ Libya, LFF, (Libya Football Federation) ni awọn ti fesi pada si iwe ti Naijiria kọ, ẹsun ti wọn fi kan awọn ati ibeere ti CAF bi wọn leere.
O ni awawi lasan ni gbogbo ọrọ to n lọ lori ayelujara pe niṣe lawọn mọ-ọn-mọ fẹẹ foju ikọ agbabọọlu Naijiria gbolẹ, tabi pe awọn fẹẹ gbẹsan ohun ti Naijiria ṣe fun ikọ agbabọọlu awọn lasiko igbesẹ kinni ifẹsẹwọnsẹ idije fun ife ẹyẹ to laami-laaka julọ nilẹ Afrika, iyẹn AFCON (African Cup of Nations) eyi to waye lọjọ kọkanla oṣu Kẹwaa yii kan naa ni papa iṣere Godswill Akpabio International Stadium, niluu Uyo, ipinlẹ Akwa Ibom. Naijiria fagba han Libya ninu ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu ami-ayo kan dondo, eyi ti Fisayọ Dele-Baṣiru gba s’awọn lọjọ naa.
Libya waa ra’wọ ẹbẹ pe ki CAF maṣe fiya jẹ awọn o, ki wọn si ba awọn bẹ Naijiria lati jeburẹ, wọn ni oju-ọjọ ti ko dara, ati abọ ayẹwo lo fa ayipada pajawiri to ṣẹlẹ si ọkọ ofurufu ti wọn yi eto ibalẹ rẹ pada lojiji naa.