Ajọ CAF to n ṣakoso ere bọọlu alafẹsẹgba ni ilẹ Africa, iyẹn Confederation of African Football, ti gbe idajọ rẹ kalẹ lori gbọnmi-si-i-omi-o-to ati awuyewuye to bẹ sílẹ laaarin ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Naijiria ati ti orileede Libya, titi kan ajọ to n dari ere bọọlu alafẹsẹgba lorileede mejeeji, wọn si ti kede idajọ wọn f’aye gbọ bayii, ifá idajọ naa ko fọ’re fun awọn Libya rara, CAF da wọn lẹbi gidigidi, wọn tun da wọn ni gbese owo nla, owo itanran.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii ni CAF ṣe ikede idajọ wọn lori abọ iwadii ti wọn ṣe si ọkan-o-jọkan ẹsun ati aṣemaṣe ti Naijiria fi kan Libya lọdọ ajọ CAF.
Ṣe ṣaaju ni ajọ to n dari ere bọọlu alafẹsẹgba ni Naijiria, Nigeria Football Federation, NFF ti kọwe ẹsun nipa iwa iwọsi, aibikita ati fifi oju ẹni rare ti awọn oludari ere bọọlu ilẹ Libya, Libya Football Federation, LFF, hu si ikọ agbabọọlu Super Eagles laaarin ọsẹ to ṣaaju, nigba ti wọn fẹẹ kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ kan lorileede Libya.
Ifẹsẹwọnsẹ ọhun to yẹ ko waye laaarin ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti ilẹ Naijiria ati ẹgbẹ agbabọọlu Mediterranean Knights ti ilẹ Libya lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa yii, ni papa iṣere Martrys Stadium, to wa ni Benina, niluu Bengazhi, lorileede Libya, fori ṣanpọn, ko le waye mọ nigba ti ikọ Super Eagles fibinu kuro lorileede Libya lọsan-an kan oru kan, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtala oṣu Kẹwaa yii, ti wọn si kọri sile.
Wọn fẹsun kan Libya pe dipo ki wọn jẹ ki ọkọ ofurufu lọọ ja awọn Super Eagles silẹ niluu Bengazhi ti wọn ti jọ fi adehun si tẹlẹ, papakọ ofurufu nla ti Al-Abraq ni wọn ja wọn si, fun ohun to ju wakati mẹrindinlogun 16) lọ si ni awọn agbabọọlu at’awọn kooṣi wọn fi laalaṣi ninu iporuuru ọkan, wọn ko rẹni fun wọn ni ounjẹ ati omi, awọn olugbalejo wọn ko yọju ki wọn kaabọ, depo-depo ki wọn pese ilegbee fun wọn.
Eyi lo mu ki wọn binu pada wale, ti wọn si fẹjọ Libya sun CAF.
Bo tilẹ jẹ pe Libya naa fesi pe ọrọ ko ri bẹẹ, sibẹ ajọ CAF ṣe iwadii, abọ iwadii naa si fihan kedere pe wọn jẹbi daadaa.
CAF ni ilẹ Libya ti ṣẹ si abala kọkanlelọgbọn (31), abala kejilelọgọrin (82) ati abala ikọkanlelaaadọjọ (151) iwe ofin to n ṣakoso idije bọọlu alafẹsẹgba fun ife-ẹyẹ AFCON to gbayi julọ nilẹ Afrika.
Tori bẹẹ, CAF ṣedajọ pe, àkọkọ, ifẹsẹwọnsẹ to yẹ ko waye naa, awọn ti ṣiro rẹ sí pe orileede Naijiria lo bori pẹlu ami ayo mẹta.
Ekeji, awọn tun ṣírò rẹ si pe ẹẹmẹta ni Naijiria gba bọọlu s’awọn Libya.
Ẹkẹta, ki Libya tọrọ aforiji lọwọ Naijiria, ki wọn si san ẹgbẹrun lọna aadọta owo dọla gẹgẹ bii owo itanran.
Amọ, CAF lawọn ko faramọ awọn ẹbẹ mi-in ti Naijiria n beere lati da sẹria fun Libya, wọn lawọn ti da iyoku nu bii omi iṣanwọ.