Itafaaji

Erin wo! Baba Agbako ti ku o!

Ajanaku sun bii oke, erin ṣubu ko le dide, bẹẹ lakukọ kọ lẹyin ọmọkunrin. Ọfọ nla ti tun ṣẹlẹ lagbo awọn oṣere tiata ilẹ Naijiria, paapaa ni ilẹ Yoruba, pẹlu bi iku alumuntu ṣe ja ọkan pataki lara wọn gba, to si pa a loju de, ogbontarigi oṣere ori itage nni, Alagba Charlse Olumọ ti gbogbo eeyan mọ si Àgbákò, o ti ki aye pe o digboṣe, lẹni ọdun mọkanlelọgọrun-un, 101 years.

Iroyin iku baba agbalagba yii kuro ni ‘ma-jẹ-a-gbọ’ pẹlu bi ọpọ awọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ ṣe tu’fọ iku ọhun lori ikanni ayelujara koowa wọn, ti wọn si ki baba naa pe ‘o digba, o di gbere!’

ITAFAAJI fidi rẹ mulẹ pe owurọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii ni Baba Agbako, ọmọ bibi ilu Abẹokuta, ni ipinlẹ Ogun yii, mi eemi ikẹyin ni ile rẹ.

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere tiata ni Naijiria, The Theatre Arts and Motion Pictures Association of Nigeria (TAMPAN), Ọgbẹni Bọlaji Amuṣan, t’awọn eeyan mọ si Mista Latin naa ti fidi iku eekan oṣere yii mulẹ.

Ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Tọsidee iṣẹlẹ ọhun, o ni: Eyi ni lati kede ipapoda Alagba Charlse Olumọ Sanyaolu, t’awọn eeyan mọ si Agbako. Ẹkunrẹrẹ alaye nipa bi eto isinku rẹ yoo ṣe lọ si maa jade laipẹ. O daarọ o, Baba. Lati ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kejì, ọdun 1923 (iyẹn ọjọ-ibi rẹ) si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024, to jade laye.

Lori ikanni Instagiraamu ilumọ-ọn-ka onitiata nni, Kunle Afod, o gbe fọto kan ti oun ati Agbako jọ ya laipẹ yii sibẹ, o si kọ ọrọ idaro sabẹ fọto naa, o ni:

O daarọ Alagba Charlse Olumọ (Baba Àgbákò).

Oṣere tiata to lọjọ lori julọ, ẹni ọdun mọkanlelọgọrun-un, 101.

Sun un’re o

O dabọ

O doju ala.

Bi Kunle Afod ṣe tufọ iku Agbako yii lawọn onitiata ẹlẹgbẹ rẹ ti n daro ọkunrin to ti ṣe gudugudu méje yaayaa mẹfa nidi iṣẹ tiata yii, ti koowa wọn si n gbe ọrọ idaro soju opo ayelujara wọn.

Biọdun Ọkẹowo, Omoborty, sọ pe: “Ki ẹ sun ire ṣa o. Ko si b’awọn ololufẹ wa ṣe le dagba to, ko kii wu wa ki wọn lọ. Afod, ọga mi, ẹ kuu afọmọniyan-ṣe o

Mercy Aigbe ati ọkọ rẹ, Alaaji Kazeem Adeoti ni: “K’Ọlọrun tẹ ọkan rẹ safẹfẹ rere o, sun ire Baba”.

Funkẹ Akindele, t’awọn eeyan mọ si Jẹnifa sọ pe: “Aaa, Ki Ọlọrun fun ọkan rẹ ni ìsinmi. Wao, Oluwa tobi lọba o. O si fi ami ifẹ sabẹ ọrọ rẹ.

ITAFAAJI yoo maa fi to ẹyin ololufẹ wa leti bi eto isinku ati ẹyẹ ikẹyin agba oṣere yii ba ṣe lọ sì.


Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search