Ṣẹyin naa ti gbọ ohun to ṣẹlẹ laaarin Nkechi Blessing ati Mista Latin ni Canada?
Titi di asiko yii ni igbesẹ akin ti ilumọ-ọn-ka oṣere tiata ilẹ wa to rẹwa daadaa nni, Abilekọ Nkechi Sunday Blessing gbe, ṣi n ya ọpọ eeyan lẹnu, nitori wọn ko ro’kàn rẹ si rara pe o le ṣe iru nnkan bẹẹ, kò si tun ṣe kinni naa labẹlẹ, bẹẹ ni ko d’aṣọ boju ṣe e, gbangba walia nibi ti ọpọ ero wa ni, ilu oniluu si tun ni, lorileede Canada lọhun-un, laaarin oun ati eekan oṣere tiata to jẹ alaga ẹgbẹ wọn, Ọgbẹni Bọlaji Amuṣan ti gbogbo eeyan mọ si Mista Latin ati awọn oṣere ẹlẹgbẹ rẹ yooku wa nikalẹ ni, koda ọrọ ohun kan Baba Ijẹṣa, Ọgbẹni James Ọlanrewaju, iyẹn gbajumọ adẹrin-in-poṣonu onitiata to wa l’ẹwọn lasiko yii.
Ṣe lati nnkan bii ọdun mẹta sẹyin ni onigbo ti da’gbo si meji laaarin ẹgbẹ awọn oṣere tiata ilẹ wa, Theater Arts and Motion Pictures Practitioners of Nigeria, TAMPAN, ọrọ ẹsun biba ọmọde ṣeṣekuṣe ti wọn fi kan Baba Ijẹṣa lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021 lo si da wahala silẹ, ti awọn oṣere tiata bẹrẹ sii sọ’ko ọrọ ati eebu si ara wọn, agaga laaarin Iyabọ Ojo ati Yọmi Fabiyi, Nkechi Blessing ati oṣere kan to tun maa n kọrin lori ẹrọ ayelujara, Adams Kẹhinde t’awọn eeyan mọ si Lẹgẹ Maimi.
Awuyewuye to gbona janjan ọhun lo mu ki awọn agbaagba ẹgbẹ TAMPAN jokoo, Ọmọọba Jide Kosọkọ lo ṣe alaga ipade naa, to si paṣẹ fawọn ọmọ ẹgbẹ yooku pe wọn kò gbọdọ ba Iyabọ Ojo ati Nkechi Blessing ṣiṣẹ mọ, wọn ko si gbọdọ tele wọn lọọ oko ere titi ti wọn yoo fi f’eegun otolo to lọgbọ-lọgbọ to n ja ranyin lasiko ọhun.
Amọ bi Nkechi ṣe gbọ ohun ti Jide at’awọn agbaagba ẹgbẹ sọ yii, niṣe lo fi awọn ati ẹgbẹ TAMPAN ṣẹlẹya, o loun wa wọn oun ko ri wọn, ati pe t’apo ara wọn ni ipinnu ti wọn ṣe naa. Latigba naa lọ ni tirela ti gba aarin oun ati ẹgbẹ TAMPAN kọja, tọrọ di konko-jabele kaluku lo n ṣe tiẹ laaarin wọn.
Asẹyinwa-asẹyinbọ, Baba Ijẹṣa r’ẹwọn he nile-ẹjọ, l’oṣu Keje, ọdun 2022, kootu da a lẹbi, wọn si la a m’ẹwọn, ọdun mẹrindinlogun ni Adajọ Oluwatoyin Taiwo ju u si ni Kirikiri. Ko si tun si ẹni to wi kinni kan mọ latigba naa, bo tilẹ jẹ pe kaluku ṣi n ṣe tiẹ lọtọ ninu ẹgbẹ onitiata.
Eyi lo mu ki iwa ti Nkechi Blessing hu lọsẹ yii fi yaayan lẹnu, nitori ko sẹni to reti pe iru igbesẹ bẹẹ yóò waye lat’ọdọ ẹ. Ninu fọran fidio kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara bayii, Nkechi Blessing bọ sori pepele nibi ayẹyẹ ti wọn ti n fi oriṣiiriṣii awọọdu da awọn oṣere tiata ilẹ wa lọla ni Canada, o loun ni ọrọ pataki lati sọ o, lo ba gba ẹrọ amohun-bu-gbẹmu, iyẹn makirofoonu, amọ bo ṣe fẹẹ sọrọ, niṣe lo kunlẹ wọ̀ọ̀ sori pepele, o ni idariji loun fẹẹ tọrọ lọwọ olori ẹgbẹ awọn, Mista Latin ati lọwọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ to ku. Kia ni Mista Latin ti sare lọọ ba Nkechi lori pepele naa, oun ati Odunlade Adekọla, t’awọn eeyan tun n pe ni Saamu Alajọ si gbiyanju lati fa a dide, wọn ni ko sọrọ rẹ lori iduro, ko ma wulẹ kunlẹ, amọ Nkechi taku, kò gba, o lori ikunlẹ loun ti fẹẹ sọrọ, ki wọn sa jẹ k’oun wa ni ikunlẹ bẹẹ, ṣe Yoruba bọ wọn ni, bi ẹlẹjọ ba ti mọ ẹjọ rẹ l’ẹbi kii pẹ lori ikunlẹ, ati pe a kii dọbalẹ ka n’ina loju, lawọn mejeeji ba duro si ẹgbẹ rẹ.
Niṣe ni Nkechi Blessing bu sẹkun bo ṣe bẹrẹ ọrọ naa, o ni: “Ẹ ma binu fun gbogbo ohun ti mo ṣe, mo tọrọ aforiji lati ọkan mi wa, ẹ fori jin mi. Àárò iṣẹ tiata ti sọ mi, mo mọ ọn lara bi mi o ṣe lọ s’oko ere. Gbogbo yin lẹ jẹ ki n di ẹni ti mo di loni-in. Bi mo ṣe di ẹni apọnle, ti gbogbo aye n gbe mi gẹ̀gẹ̀ ko ṣẹyin yin. Ẹ fori jin mi, mo tuuba.” Bẹẹ lomije n da loju rẹ.
Bo ṣe sọrọ tan ni awọn ẹlẹgbẹ rẹ patẹwọ fun un, wọn fa a dide, wọn si gba a mọra, Mista Latin si gba makirofoonu lati kede pe ẹgbẹ ti dari ji i, ko jẹ k’awọn maa kọ́mọlùbọ́ niṣo.
Nkechi ko fi ọrọ naa mọ sibẹ o, lọjọ keji, o tun gba ori ẹrọ ayelujara lọ, lori ikanni Instagiraamu rẹ, lati fihan pe tinutinu ati tọkantọkan ni aforiji toun tọrọ naa, o si kọ ọrọ sibẹ pe abamọ kii ṣaaju ọrọ, o ni ka sọ pe oun ti mọ awọn ohun ti oun waa mọ bayii tẹlẹ ni, oun ìbá má ti ṣe boun ṣe ṣe nigba yẹn. Ṣugbọn oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun itọsọna ati idari rẹ laye oun. O tun tọrọ aforiji lọwọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, o loun bẹ wọn, oun si gbagbọ pe wọn yoo rò o l’ọkan wọn lati dari ji oun.
O daju pe inu ọpọ awọn onitiata ẹlẹgbẹ rẹ at’awọn ololufẹ rẹ dun gidigidi si igbesẹ ti Nkechi gbe yii. Eyi fara han ninu bi wọn ṣe rọ’jo ọrọ oriyin, ifẹ ati igboṣuba-funni si oṣere-binrin apọnbeporẹ to lomi lara daadaa yii.
Lẹyẹ-o-sọka ni awọn irawọ oṣere tiata bii Iyabọ Ojo, Adebimpe Akintunde, iyawo Lateef Adedimeji ti wọn tun n pe ni Mo Bimpe, Yewande Adekọya Abiọdun, Kẹmi Korede, Jamiu Azeez ati Oge Okoye ti fi ami ifẹ ranṣẹ si Nkechi labẹ ọrọ to sọ ọhun.
Agba-ọjẹ onitiata nni, Ọmọọba Jide Kosọkọ to fẹran lati maa daṣa Omfridoma ninu fiimu rẹ naa ti fesi lori ọrọ yii, o ni: Nkechi, ni t’ododo, a ti dari ji ẹ, koda a ti ṣe bẹẹ ki Aarẹ ẹgbẹ wa too sọrọ jade. A o gbe igbesẹ lati yọ ẹ lẹgbẹ wa o, mo mọ iyẹn daadaa. Ọmọ mi lo jẹ, Ọlọrun Olodumare a si maa ṣọ e, a a maa to ẹ s’ọna. Amin.
Dele Odule ni tiẹ sọ pe ohun ti Nkechi Blessing ṣe yii tubọ mu ori oun wu, o si waa jẹ k’oun fẹran ẹ. O ni loootọ oun kii saaba sọrọ tabi kọ ọrọ sori ẹrọ ayelujara amọ nitori bi inu oun ṣe dun si iwa ti Nkechi hu yii loun fi fesi, tori iwa agba lo hu.
Ọrọ ṣoki, ọrọ adura ati oriyin lawọn mi-in kọ lati
Toyọsi Adesanya ni: Ọlọrun a tubọ maa dari akitiyan ẹ o.
Yinka Quadri ti wọn n pe ni Masọmọ, fesi pe: “O ṣe daadaa o”
Georgina Ibeh ni: “Ọlọrun aa bukun ẹ”