Itafaaji

Lẹyin Baba Agbako, gbajumọ oṣere tiata mi-in tun dagbere faye!

Leyii ti ko tii to ọsẹ kan ti eekan oṣere tiata ilẹ Yoruba ti wọn loun lo lọjọ lori ju lọ laarin wọn, Alagba Charlse Olumọ Sanyaolu t’awọn eeyan mọ si Baba Agbako tẹri gbaṣọ, gbajumọ onitiata mi-in, to kopa to jọju ju lọ ninu fiimu Tunderbolt, tabi Magun, Ọgbẹni Wale Macaulay ti ki aye pe o digboṣe.

Oniroyin ori ẹrọ ayelujara kan, Ṣeun Oloketuyi, lonfifi iṣẹlẹ yii mulẹ lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keje, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii lori ikanni rẹ.

Titi dasiko ta a fi n kọ ìròyìn yii jọ, ko tii si ẹkunrẹrẹ alaye kan nipa ohun to ṣokunfa iku ojiji ọkunrin naa, amọ ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ti wọn ṣi jẹrii pe ootọ ni.

Adewale Adisa Macaulay lo kopa agunbanirọ to yofẹẹ fun ọdọmọbinrin kan to n gbe lọdọ Mama Bukky Ajayi to ti doloogbe bayii, ninu fiimu agbelewo Tunderbolt ti Alagba Tunde Kelani ati ileeṣẹ Mainframe Productions (Opomulero) gbe jade lọdun 2001.

Bakan naa ni Oloogbe yii kopa to jọju ninu awọn fiimu agbelewo elede oyinbo bii Accident ati Protégé, ti wọn gbe jade lọdun 2013, ere Yoruba abalaye O le ku! t’ọdun 1997, Most Wanted apa kinni ati ikeji, Violated, Small Boy, ati ere ori tẹlifisan aye ọjọun, Unbroken.

Oloogbe yii tun ni Oludasilẹ ẹgbẹ akọrin kan to pe ni Kazimba Musical Group, o dari ere ori itage eyi ti wọn gbe jade ni MUSON Centre, l’Ekoo, Rape of Gidiolu ni wọn pe akọle ere naa.

Ọgọọrọ awọn ololufẹ oṣere yii ni wọn ti n ṣedaro rẹ, ti wọn ṣi n ba awọn mọlẹbi rẹ kẹdun, wọn ṣadura pe ọjọ aa jinna sira o.


Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search