Apọnbeporẹ, Olori Damilọla, tii ṣe ọkan ninu awọn olori ti Alaafin Ọyọ, Iku Baba Yeye, Ọba Lamidi Adeyẹmi fi s’aye lọ, ti gbe ọrọ amọran kan soju opo ayelujara rẹ, awọn eeyan to mọ bo ṣe n lọ si ti sọ pe ọrẹkunrin rẹ, to n ṣe ‘Baba ibẹ’ fun un lẹyin iku Alaafin lo n ọrọ naa bawi, wọn ni Portable olorin Zah zuuuh zeh, Habeeb Okikiọla ọmọ Ọlalọmi lo n ta sí.
Ṣe lati bii ọjọ mẹta kan ni lọgbọ-lọgbọ ti n ṣẹlẹ laaarin awọn ololufẹ mejeeji yii, Portable ko si fi ọrọ ohun bo, gbogbo bo ṣe n lọ laaarin oun ati Olori Dami, ati ọmọ to bi fun Alaafin ni olorin to fẹran lati maa daṣa ‘wahala, wahala, wahala’ yii n tẹ pẹpẹ rẹ sori intanẹẹti fawọn ololufẹ rẹ.
Laipẹ yii ni Portable, to tun maa n pe ara rẹ ni Idaamu Adugbo yii, ṣalaye lori ikanni Instagiraamu rẹ pe wahala iyawo Alaafin yii ti fẹẹ pọ ju toun lọ, o lobinrin naa ni igbonara, o si n jowu, o fẹsun kan an pe o ja wọ ile ọti oun, iyẹn Odogwu Bar, o si le awọn obinrin to wa nibẹ danu, awọn ‘gbele-pa’wo’ to n ṣ’ọrọ-aje nile ọti oun.
Portable ni ni toun oun o tori obinrin kan dá’kó, Olori Dami kọ làkọ́fẹ́ oun, ko si le k’oun ma fẹ ẹlomi-in le oun.
Bẹẹ lo tun ṣalaye pe gbogbo atijẹ-atimu ọmọ Alaafin to gbe waa fẹ oun, oun loun n gbọ gbogbo bukata atiya-atọmọ, sibẹ ti ko mọ ọn foun, o ni ko moore.
Gbogbo ẹsun yii ni Olori Dami paṣamọ mọ ninu ọrọ iṣinileti kan to gbe sori ikanni rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii.
Bayii ni Olori Dami ṣe kọ ọrọ rẹ, o ni: “Keeyan ni igbẹkẹle ninu ara rẹ gan-gan leeyan fi le ri aye gbe. Ko si mimi to lé mi ọ too ba ti mọ bo o ti n ṣe n ba a bọ. Ti ẹmi ba wa, ireti n bẹ.
O tun sọ ninu ọrọ mi-in pé: “Ni temi o, mi o raaye fun ohunkohun ti maa ba mi ninu jẹ.”
Amọ ninu ọrọ ti awọn ololufẹ Olori Dami yii kọ sabẹ fọto rẹ, ko jọ pe wọn ri ti aroye rẹ ro rara, kaka bee, ẹwa rẹ ati iṣaraloge obinrin to n dan dii digi yii ni wọn n ri, ọpọ wọn lo si n jowu Portable, wọn ni ko si aṣadanu ninu awọn iyawo rẹ, gbogbo wọn lo j’oju-ni-gbese daadaa.