Oniroyin ori ẹrọ ayelujara kan, Nollywood Citadel lo kọkọ ṣofofo iroyin ayọ ọhun lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii, loju opo Instagiraamu rẹ, nibẹ lo kọ ọ si pe: “A gbọ pe oṣere-binrin Dayọ Amusa ti bimọ lanti-lanti kan s’orilẹ-ede United States of America o. A ki i kuu oriire o!”
Bakan naa tun ni oniroyin mi-in, Ṣeun Oloketuyi tun fidi iroyin ayọ yii mulẹ, o sọ loju opo ayelujara rẹ pe “Dayọ Amusa ti bimọ l’Amẹrika, a kuu oriire o.
Ṣe inu ẹni kii dun ka pa a mọra, lọsan-an ọjọ Mọnde ọhun, niṣe ni Dayọ Amusa gbe fọto ikoko jojolo naa si ori ikanni rẹ, o gbe orin oṣere-binrin akọrin ẹmi nni, Adeyinka Alaṣeyọri si i, nibi to ti kọrin pe:
“Ohun t’aye pe ni pipẹ, yiya ni lọdọ rẹ.
Aa, wọn ro pe o pẹẹ de, aṣe niṣe lo tete de.
Oo kii pẹ ẹ de, oo kii tete De o, Akoko to tọ lo maa n de.
Bi wọn ba n pe ọ lagan, ma wo’bẹ o, bi wọn ba n pe o lagan ma wo’bẹ o, ati bẹẹ bẹẹ lọ.”
Ṣe bi Dayọ ti ṣe wa ni ipo aboyun-mọ-oṣu-ko-mọ-ọjọ, ti asiko irọbi rẹ ti n sunmọle lo ti n rawọ ẹbẹ to si n dupẹ lọwọ Ọlọrun tadura-tadura, pẹlu awọn orin ọlọkan-o-jọkan to maa n gbe si i.
Nigba t’adura rẹ si gba yii, labẹ fọto to gbe soju opo Instagiraamu naa, o kọ ọrọ ikede ayọ rẹ sibẹ, o ni: “Allihamudulilahi. Iṣura iyebiye mi ti de o. Ọmọkunrin ni o”. O si fi ami idupẹ sibẹ.
Tidunnu-tidunnu lawọn eeyan fi n yayọ ọmọ tuntun ti Dayọ bi yii, ọpọ lo si n kan saara si Ọlọrun pe Oun nikan ni Ọba to n sọ àgàn di ọlọmọ, ati pe Olodumare ko gbagbe ẹnikan.
Aka-i-ka-tan lawọn oṣere ti wọn ti ki iya ikoko tuntun yii kuu ewu, bi wọn ti n ba a yọ ni wọn tun n ba a dupẹ lọwọ Eledua to ṣe ọjọ ikunlẹ rẹ ni irọrun fún un, t’agbe ko fọ, t’omi ko si danu, taa gbohun iya taa gbohun ọmọ. Lara wọn ni Toyin Abrahamu, ti wọn n pe ni Iya Ire, Iyabọ Ojo, Gabriel Afọlayan, Bukola Arugba, Omowunmi Ajiboye, Abiola Ajibayo t’awọn eeyan mọ sí Eyin Ọka, Ọmọọba Adebimpe Oyebade, ìyẹn iyawo Lateef Adedimeji ti wọn tun n pe ni Mo Bimpe, Jide Awobọna, Adẹrin-in-poṣonu Bunkunmi Adeaga-Ilọri ti ọpọ eeyan mọ si Kie-Kie, Lola Margaret, Eniola Ajao, Bukola Adeẹyọ, Wumi Toriọla, Adeniyi Johnson, Bidemi Kosọkọ, Omowunmi Da-Silva, Laide Bakare, Bimbo Thomas, Toyin Adewale, Adẹrin-in-poṣonu Olatayọ Amokade t’awọn eeyan mọ si Ijẹbu, Akinyọọla Ayoola ti wọn n pe ni Officer Kamo, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Itafaaji naa n ki Dayọ Amusa kuu ewu o, a ṣadura pe Ọlọrun aa wo o, yóò sí lọwọ rere lẹyin o.