Itafaaji

Eyi nidi t’ile-ẹjọ fi yọ MC Oluọmọ nipo Aarẹ ẹgbẹ onimọto

Lai wo ti bi òjò ikini kuu oriire ati idawọọ idunnu ṣe n rọ̀ sori ikanni ayelujara Olori ẹgbẹ awọn onimọto ero, National Union of Road Transport Workers (NURTW) ti wọn tun n pe ni ẹgbẹ National, ẹka ti ilu Eko tẹlẹri, Alaaji Musiliu Ayinde Akinsanya, ti gbogbo eeyan mọ si MC Oluọmọ lasiko yii, fun ti iyansipo ati ibura-wọle rẹ sipo Olori yan-an-yan-an ẹgbẹ naa, iyẹn Aarẹ National to ṣẹṣẹ bọ si ni ibẹrẹ ọsẹ to lọ yii, ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun (Court of Appeal) kan, to fikalẹ siluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa ti paṣẹ pe ni kiamọsa, ki MC Oluọmọ maṣe pe ara rẹ ni Aarẹ National kankan, bẹẹ ni ko tii gbọdọ jokoo sipo Olori apapọ ẹgbẹ NURTW ọhun, nitori loju ofin, oun kọ ni Olori ẹgbẹ naa, wọn ni Alaaji Tajudeen Ibikunle Baruwa ni Aarẹ ẹgbẹ ọhun, oun ni ofin mọ, iṣakoso rẹ lo si wa nibaamu pẹlu ofin ni saa yii.

Ile-ẹjọ naa tun paṣẹ pe gbọin-gbọin lawọn duro lẹyin idajọ ile-ẹjọ to maa n yanju aawọ laaarin ileeṣẹ, oṣiṣẹ ati ẹlẹgbẹ-jẹgbẹ, iyẹn National Industrial Court, awọn ko si ri aleebu kan ninu idajọ ti kootu naa gbe kalẹ lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2024, ninu eyi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe Baruwa ni Aarẹ ẹgbẹ National ti iyansipo rẹ b’ofin mu.

Nigba ti Alaaji Tajudeen Baruwa n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii niluu Abuja, ọkunrin naa b’ẹnu àtẹ́ lu iyansipo MC Oluọmọ sipo Aarẹ ẹgbẹ, ati bi wọn ṣe bura wọle fun un, Baruwa ni gbogbo iṣẹlẹ ọhun paayan l’ẹrin-in, tori ko yatọ si bii igba ti wọn n ṣe awada kẹrikẹri, o ni gbogbo kinni naa ko ba ofin mu pẹ́ẹ̀, o tako ofin, o tako idajọ, koda o ri awọn adajọ fín pẹlu.

Baruwa ṣalaye pe idajọ meji ọtọọtọ lawọn to wa nidii iyansipo MC Oluọmọ ọhun tasẹ agẹrẹ si, idajọ ti National Industrial Court ti ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun yii, ati idajọ ti ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to waye lọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii, nibi ti wọn ti paṣẹ pe ki igun ti Alaaji Nojeem Yasin ati awọn ẹmẹwa lọọ so ewe agbejẹẹ m’ọwọ, ki wọn lọọ wa’bi jokoo si, wọn ko gbọdọ da si ohunkohun ninu eto iṣakoso ẹgbẹ National, ko si s’ohun to kan wọn ninu bi Alaaji Baruwa ati igbimọ rẹ ṣe n tukọ ẹgbẹ naa.

Tẹẹ o ba gbagbe, nigba ti awuyewuye dide lori iyansipo Alaaji Baruwa gẹgẹ bii Aarẹ ẹgbẹ National, ti awọn kan fẹẹ fi tipa yẹ aga mọ ọn nidii ni ọkunrin naa kọ’ri s’ile-ẹjọ lati gbeja ipo rẹ, ti National Industrial Court si da a lare.

Eyi ko tẹ awọn opomulero ẹgbẹ ọhun kan lọrun, bii Alaaji Najeem Usman Yasin, Alaaji Tajudeen Agbẹdẹ at’awọn ẹmẹwa wọn, lawọn naa ba gba ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lọ, pe ki wọn b’awọn wọgi le idajọ to ṣègbè lẹyin Baruwa naa, amọ ifa ko fọ’re fun wọn.

Afi bi ariwo ṣe gbode lojiji lopin ọsẹ to kọja pe wọn ti yan MC Oluọmọ sipo Aarẹ ẹgbẹ ọhun, ki oloju si too ṣẹ ẹ, wọn ti bura fun un lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii, oun at’awọn igbimọ rẹ.

Baruwa ṣalaye pe ẹgbẹ awọn ni iwe ofin ati ilana ti wọn n tẹle, paapaa lori to ba di ọrọ yiyan awọn adari ẹgbẹ sipo.

Nitori eyi, o ke si Ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, IGP Kayọde Egbetokun, Minisita fun eto idajọ, Oloye Lateef Fagbemi, ati awọn agbofinro gbogbo lati tete da si lọgbọ-lọgbọ to n lọ ninu ẹgbẹ naa ki alaafia ati aabo le jọba, ati ki ofin le r’ẹsẹ walẹ bo ṣe tọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search