Ṣe Yoruba bọ, wọn ni ibẹrẹ ija la a mọ, ko s’ẹni tii mọ ibi ti ija yoo pari si, sibẹ inu idunnu ni ọpọ awọn ololufẹ gbajugbaja oṣere ilẹ wa meji, Ẹniọla Badmus ati David Adeleke, wa bayii, latari bi awọn mejeeji ṣe ṣafihan ni gbangba pe aawọ to wa laaarin wọn ti lọ s’okun igbagbe, awọn ti pari ija, awọn si ti di ọrẹ pada bii ti atẹyinwa.
Bo tilẹ jẹ pe awọn kan n sọ pe ija naa ko ṣẹṣẹ pari, pe wọn ti pari ọrọ labẹ aṣọ tipẹtipẹ, sibẹ asiko to han sí gbogbo aye pe Davido ati Ẹniọla ti tun di ọrẹ pada ni ti iṣẹlẹ to waye lopin ọsẹ to kọja yii.
Gbajumọ oṣere tiata ilẹ wa to ri mugbẹ-mugbẹ nni, Ẹniọla Badmus, t’awọn eeyan tun maa n pe ni Wule Bantu, ati ilumọ-ọn-ka onkọrin hipọọpu nni, David Adeleke, t’awọn eeyan tun n pe ni Davido, wa lara awọn alejo pataki ti wọn fi ijokoo yẹ Ojiṣẹ Ọlọrun, Pasitọ Tobi Adegboyega si, fún ti ayẹyẹ ọjọ-ibi ọdun kẹrinlelogoji (44) rẹ. Orilẹ-ede United Kingdom ni wọn tẹ pẹpẹ ariya nla naa si lọjọ kọkànlá, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii, pati nla ti ọpọ awọn oṣere, oloṣelu ati ọtọkulu pesẹ si, faaji famia ti ojo owo dola ti pound sterling ti rọ bii omi ni.
Lara awọn oṣere mi-in to wa nikalẹ ni Nkechi Blessing, Ọlakunle Churchill, Daddy Freeze, Toyin Lawani ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ṣa, gẹgẹ bo ṣe han ninu fọran fidio kan ti Ẹniọla gbe soju opo Instagiraamu rẹ lori ẹrọ ayelujara, Ẹniọla ati Davido di mọra, wọn ṣi tun bọ ara wọn lọwọ nigba ti wọn pade, eyi si mu inu ọpọ awọn onworan to wa nibẹ dun, bo tilẹ jẹ pe oriṣiiriṣii iran lo ṣẹlẹ nibi ariya naa, iru-wa-ogiri-wa si lawọn ero to wa nibẹ.
Nigba to ya, Ẹniọla tun dagbere fun Davido, o si fun un oun atiẹ maa sọrọ lori aago, o loun aa pe e, iyẹn si loun ti gbọ, oun aa maa reti.
Tẹ o ba gbagbe, latigba ti ọmọ Davido ọkunrin, Ifeanyi, akọbi ti iyawo rẹ, Chioma, bi fun un ti kagbako iku ojiji lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 ni aawọ ti bẹ silẹ laaarin Davido ati Ẹniọla, ti wọn jẹ ọrẹ korikosun tẹlẹ. Wọn ni ipá ti Wule Bantu ko lasiko ti ọfọ naa ṣẹ, pẹlu bi ṣe sare kede to si gbe fọto ọmọ ọhun sori ayelujara, lo bi awọn obi ọmọ naa ninu. Lẹyin eyi ni Davido ati Chioma yọ ara wọn kuro lori gbogbo ikanni to jẹ ti Ẹniọla Badmus.
Bakan naa lawọn eeyan bú ẹnu atẹ lu Ẹniọla Badmus nigba to ṣẹri pada wale lati ibí afihan ati ikojade orin Davido tuntun to pe akọle rẹ ni Timeless lọdun to kọja, wọn ni tori ija aarin wọn lo ṣe ṣe bẹẹ.
Lati fi bi inu wọn ṣe dun to si ija to pari yii, oriṣiiriṣii ọrọ lawọn ololufẹ wọn kọ sabẹ fidio ti Ẹniọla ṣafihan rẹ. Ẹnikan ni: “Inu mi dun gan-an lati ri i pe iwọ ati Davido bọ ara yin lọwọ o”.
Seunblues_1 sọ pe: Ọlọrun o ṣeun o, mo ri oun ati Davido ti wọn bọ ara wọn lọwọ.”
Hannie__06 ni: “Mo layọ lati ri Aunti Ẹni ati David papọ lẹẹkan si i.”
Ọlayinka debbs sọ pe: “Bi ija yii ṣe pari dun mọ mi ninu gidigidi, aa Ọlọrun maa bu kun ẹyin mejeeji nigba gbogbo.”