Ibeere kan to n ja ranyin lete awọn ololufẹ fiimu agbelewo, paapaa awọn ti wọn gba ti oṣere-binrin to gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta nni, Toyin Abrahamu, t’awọn eeyan tun n pe ni Iya Ire ni pe ‘ṣe loootọ ni Iya Ire ti loyun?’
Kii kuku ṣe wipe obinrin naa kere oyun nini o, ile ọkọ lo wa, ọmọ rẹ, Ire, si ti kuro ni agbekọrun-roko, o ti dagba to lati gba aburo daadaa, nitori bẹẹ, awọn to n ṣe kayeefi yii ko rokan aburu si Toyin rara, ohun ti wọn ri ninu fidio kan ti oṣere-binrin naa ju sori afẹfẹ lo jọ pe o ru ọpọ eeyan loju.
Loju opo ayelujara Instagiraamu rẹ, lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla taa wa yii, ni Toyin Abrahamu gbe fidio kan si, nibi to ti wọ’ṣọ pupa rẹsu-rẹsu, oyún wa nikun rẹ, koda niṣe lo dabi alaboyun to maa bímọ toni-tọla, tori nise lo loyun gẹ̀ru-gẹ̀ru.
Bi ọkọ rẹ si ṣe fọwọ pa oyun naa bii igba ti tọkọtaya n da gbẹ́gbẹ́lúkẹ́, bẹẹ ni Toyin n sọ fun pe ko rọra o, ko ma gba oun nikun tori alaboyun loun. O tun sọ pe ‘ẹ ma post fidio yii o, mi o fẹ ki wọn mọ pe mo ti loyun o’, loun ati ọkọ rẹ ba ku sẹrin-in.
B’awọn eeyan ṣe ri fidio yii ni wọn ti bẹrẹ sii ki Toyin pe ni kiki ti Yoruba maa n ki alaboyun, wọn ni yoo sọ asọkalẹ anfaani, pe yoo sọ layọ, awọn kan ni oyun ibeji leyi t’awọn n wo nikun rẹ yii o, o daju pe aburo meji ni yoo tẹle Ire niyẹn.
Bẹẹ si lawọn mi-in n beere pe laaarin ọjọ wo sí ọjọ wo, igba wo lawọn ṣi ri Toyin Alakada k’ẹyin na, ti ko si ami oyun lara rẹ, to si fi waa di pe o ti yara fẹraku, ikun rẹ fẹrẹ maa wọlẹ bayii.
Amọ ṣa o, Toyin ko jẹ ki awuyewuye naa lọ jinna to fi b’omi pana rẹ. Ninu ọrọ kan to kọ sabẹ fidio naa, o kọkọ pọn ọkọ rẹ le o ni:
“Ọkọ mi, ọlọrun kekere, baba mi, alaye mi, eeyan mi, olowo ori mi, olutọna mi lẹyin Ọlọrun, olukọ mi, baba awọn ọmọ mi, o ṣeun bebi mi, o si kuu ajọyọ ayajọ awọn ọkunrin kari aye o, Kolawole Ajeyemi.”
Lẹyin naa lo sọ pe: “Emi o loyun o, eyi tẹẹ ri yii, tori fiimu Alakada bad and boujee ni o”.
Sibẹ bi Toyin Abraham ṣe pariwo to yii naa, awọn tiẹ ko dakẹ lati sọ fun un pe ibeji lawọn n reti lat’ọdọ oun atọkọ rẹ Kolawọle Ajeyẹmi, toun naa jẹ irawọ oṣere tiata.
Classic ohunnene sọ pe: Toyin, ṣa ti bi ibeji si Atalanta, Georgia o.
Imọlẹ_kiki_adua ni: Toyin, Oluwa maa buwọ lu o si maa fountẹ jan ibeji fun ẹ lọdun 2025 yii o.”
Ati bẹẹ bẹẹ lọ.