Itafaaji

Wọn l’orin ti Saheed Oṣupa ṣẹṣẹ kọ yii, orin ija ni o!

Awuyewuye tuntun to n lọ n’igboro ati lori ẹrọ ayelujara lasiko yii, agaga laaarin awọn onifuji at’awọn ololufẹ orin naa ko ṣẹyin ọrọ t’awọn kan n sọ pe ogbontarigi onkọrin Fuji t’awọn eeyan mọ bii ẹni m’owo nni, Saheed Babatunde Akorede, ti ọpọ mọ si Saheed Oṣupa lo fẹẹ da wahala ati ija mi-in silẹ, wọn ni orin tuntun kan to ṣẹṣẹ gbe jade lọsẹ to kọja yii, niṣe lo fi orin naa finran, wọn l’orin ija ni.

Ṣe ṣaaju asiko yii ni lọgbọ-lọgbọ kan ti n ṣẹlẹ lagbo Fuji, laaarin gbajumọ olorin Fuji to fi ilu Ibadan ṣe ibujokoo nni, Taye Akande Adebisi, t’awọn eeyan mọ si Taye Currency tabi Taye Paso, ati eekan olorin Fuji ilu Eko nni, Wasiu Alabi Ọdẹtọla, ti gbogbo eeyan mọ si Alabi Pasuma tabi Paso.

Taye Currency ti ọpọ gbagbọ pe ọmọlẹyin Pasuma ni i ṣe latari bo ṣe maa n kọrin bii ti ọga rẹ, lo sọrọ kan to da wahala silẹ, o ni k’awọn ololufẹ oun yee pe Paso ni baba oun nidii iṣẹ Fuji, o ni loootọ loun kọrin bii Paso, amọ ko si ibi ti Paso ti kọrin de toun naa ko tii de ri, awọn ibikan si wa toun ti de ti Pasuma ko tii wọ ibẹ.

Ọrọ yii da ọpọ awuyewuye ati fa-n-fa silẹ laaarin awọn ololufẹ wọn.

Bi ina ọrọ ohun ṣe n jo gere-gere, agba onkọrin Fuji nni, Kọlawọle Ilọri ti ọpọ mọ si Kollington Ayinla, Kebe n Kwara da si i, lẹyin naa ni fidio kan hande, nibi ti Oluaye Fuji, Wasiu Ayinde Ọmọgbọlahan, Kwam1, ti n ba Taye Currency sọrọ nile rẹ, ni yara idana (kitchen) ni Wasiu ati Currency ti sọrọ lọjọ naa, Wasiu si ni ki Currency tọrọ aforiji lọwọ Pasuma, ẹyin eyi ni Currency na’wo fun Kwam1 lọjọ naa.

Bi awọn kan ṣe n ro pe ina aawọ yii ti n rọlẹ, pe ko s’ogun mọ, ko s’ọtẹ mọ, ni Saheed Oṣupa, Olufimọ akọkọ, ju orin tuntun kan sori afẹfẹ. O duro siwaju ile awoṣifila funfun ringindin kan, lo ba t’ẹnu bọ orin, o ni oun mọ ohun ti ọpọ eeyan ko mọ lagboole Fuji yii, o loun mọ awọn nnkan to jẹ tuntun ateyi to jẹ ti atijọ, lo ba darukọ Pasuma, o pe e ni Anọbi Paso, o darukọ ara ẹ, Anọbi Oṣupa, o darukọ Obesere, Ọba Alaṣakaṣa, ati Barusati, iyẹn Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister, o tan.

Orin yii lo mu k’awọn eeyan maa beere pe ‘ibo la tun ja sí yii?’ gẹgẹ bii aṣa ode oni. Wọn ni ina ija tuntun ni orin naa da silẹ latari bi Saheed Oṣupa ko ṣe darukọ Kollington, ti ko si tiẹ mẹnuba Wasiu Ayinde rara. Awọn kan ni o mọ-ọn-mọ ni, wọn ni inu n bi Oṣupa si Kwam1 ni, nitori bo ṣe gba owo lọwọ Taye Currency lati b’awọn pari ija lọjọsi, wọn ni Oṣupa sọ pe Wasiu ti fẹran owo ju!

Bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ko yẹ ki Saheed Oṣupa kọ iru orin bayii lasiko yii, bo ba ṣi kọ ọ, ko yẹ ko ju u s’afẹfẹ nigba ti ina ija ti wọn n b’omi pa labẹnu lọwọ ko tii ku.

Ṣa, awọn ololufẹ Saridon Papa, iyẹn Saheed Oṣupa ti n gbeja rẹ o. Wọn l’orin to kọ ko kan ija to wa nilẹ, bi ko sí ṣe darukọ Wasiu ati Kollington ki i ṣe ti ọtẹ, tori ko si ohun to kan an ninu ọrọ Paso ati Currency rara, ọtọọtọ lọrọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search