Itafaaji

Eyi lohun to yẹ ko o mọ nipa Adajọ agba Naijiria, Kudirat Kekere-Ẹkun

Manigbagbe ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii ninu itan oṣelu ati ti ẹka eto idajọ nilẹ Naijiria, latari bi ijọba apapọ ṣe fitan balẹ, wọn yan onidaajọ agba tuntun fun ilẹ wa, Abilekọ Kudirat Motọnmọri Ọlatokunbọ Kekere-Ẹkun sipo, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu si ṣebura-wọle fun un.

Eyi ni igba keji ti obinrin yoo di Olori ẹka eto idajọ nilẹ Naijiria latigba t’orileede naa ti gba ominira. Abilekọ Aloma Mariam Mukhtar, ti Aarẹ ana, Goodluck Ebele Jonathan yan sipo Olori ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa l’oṣu Keje, ọdun 2012, ni obinrin akọkọ ti yoo di ipo pataki ọhun mu, ọdun meji lo si fi lo o.

Ta ni Abilekọ Kudirat Kekere-Ẹkun yii? Ọmọ ilu wo ni? Ki si ni itan igbesi-aye rẹ?

Orileede United Kingdom ni wọn bi mama agbalagba yii si lọjọ keje, oṣu Karun-un, ọdun 1958, ọdun yii lo si di ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrin (66) loke eepẹ. Ọmọ bibi ilu Eko ni, Lọọya to da-n-tọ ni Baba rẹ, Alaaji Hassan Adisa Babatunde Faṣinro, o si ti figba kan wa nipo sẹnetọ laye oṣelu ọjọun, ọkan pataki lo jẹ lara awọn lookọ-lookọ ilu Eko. Musulumi ododo si ni pẹlu.

Amọ Iya rẹ, Abilekọ Winifred Layiwọla Ogundimu wa lati idile Savage, ẹlẹsin Kristẹni gidi, ẹkọ nipa iṣẹ nọọsi lo kẹkọọ rẹ niluu oyinbo, o si tun ṣiṣẹ ijọba l’Ekoo, lọdun 1965 nigba to pada siluu Naijiria.

Onidaajọ agba Kudirat Kekere-Ẹkun lọọ ileewe alakọọbẹrẹ aladaani kan, ko too kọja sileewe girama Queen’s College to wa l’Erekuṣu Eko lọdun 1970, iyẹn ileewe ijọba apapọ tawọn akẹkọọbinrin fẹran lati kawe nibẹ laye igba yẹn ni.

Ọdun 1977 lo wọ Yunifasiti Eko, University of Lagos, UNILAG, o kẹkọọ imọ ofin, o si gboye jade ni 1980, ẹyin naa lo wọ Nigeria Law School, to si ṣe tan lọdun 1981, ọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun naa lo dara pọ mọ ajọ awọn amofin ilẹ wa, o ṣiṣẹ aṣesinlu gẹgẹ bii agunbanirọ (National Youth Service Corps) NYSC, lọdun 1981 si 1982 nipinlẹ Bendel atijọ, eyi to ti di ipinlẹ Edo bayii. Lẹyin naa lo gboye Master ninu imọ ofin lọdun 1983.

Irin-ajo Abilekọ Kekere-Ẹkun lẹka eto idajọ bẹrẹ loṣu Kejila, ọdun 1989 ti ijọba ipinlẹ Eko yan an sipo Adajọ majisireeti keji, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 1996 lo gba igbega sipo Adajọ ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko.

Lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2004, o tun gba igbega sipo adajọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, ipo yii si mu ko dajọ ni ipinlẹ bii Ondo ati Benue, ko too di ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2013 ti Kekere-Ẹkun tun gun akasọ oriire mi-in, wọn sọ ọ di ọkan lara awọn adajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, iyẹn Supreme Court, oun si ni obinrin karun-un to maa niru anfaani bẹẹ nigba yẹn.

Ni ti iriri, gambari jẹ diẹ l’obi keyin too pọn. Meloo la o ka ninu eyin adipele ni ti awọn ipo pataki ti obinrin yii ti ṣiṣẹsin lẹka eto idajọ. Oun ni ijọba ologun yan gẹgẹ bii alaga igbimọ onidaajọ to n ri si ẹsun idigunjale ati kiko nnkan ija ogun kiri lọdun 1996, ilu Ikẹja, nipinlẹ Eko ni wọn fi ṣe ibujokoo nigba yẹn.

Obinrin yii wa lara awọn adajọ mẹta ti wọn n gbọ ẹsun to ba jẹ mọ gbigba ọna ẹburu ko owo ilẹ wa pamọ silẹ okeere, labẹ ofin ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, atawọn ipo mi-in bẹẹ.

Nigba to de ipo adajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ, Abilekọ Kekere-Ẹkun lo fi idajọ juwe ọna ile fun Gomina Emeka Ihedioha ni ipinlẹ Imo ̀ọjọ kẹrinla, oṣu Kinni, ọdun 2020, to si fi gomina Hope Odidika Uzodima rọpo rẹ titi di ba a ṣe n sọ yii.

Adajọ yii naa lo bu omi pa ina awuyewuye to ṣẹlẹ l’ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ati Yahaya Bello ti wọn ta ko Sẹnetọ James Faleke nipinlẹ Kogi lẹyin iku Oloogbe Abubakar Audu to wọle ibo sipo gomina, amọ to ku lojiji lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2015, ki ọjọ iburawọle too de.

Kekere-Ẹkun yii naa lo dajọ to fẹyin Ademọla Adeleke janlẹ lọdun 2020, lasiko toun ati Gomina ipinlẹ Ọsun ana, Gboyega Oyetọla jọ n ṣe fa-n-fa ipo naa.

Bi Gomina ipinlẹ Rivers ana, Amofin Nyesom Wike ṣe depo naa ko ṣẹyin Adajọ Kekere-Ẹkun, oun lo wọgi le ijawe olubori Dakuku Peterside lọdun 2016, to si da idajọ igbimọ tiribuna ati ti ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to ti waye ṣaaju nu bii omi iṣanwọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search