Itafaaji

Ija agba lagbo Fuji: Ṣẹyin naa ti gbọ orin ti Saheed Oṣupa ṣẹṣẹ kọ?

Ko si ọrọ meji to tun n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara ati nigboro, agaga laaarin awọn to fẹran orin Fuji, at’awọn ololufẹ ogbontarigi onkọrin Fuji nni, Saheed Akorede Babatunde Okunọla ti ọpọ eeyan mọ sí Saheed Oṣupa, Olufimọ akọkọ, ju ti orin tuntun kan to ṣẹṣẹ kọ laaarin ọsẹ yii lọ, orin naa ti di tọrọ fọn-ka’le bayii, o si ti da awuyewuye silẹ gidi, pẹlu bi ọpọ eeyan ṣe sọ pe ko si ani-ani kankan nibẹ, Agba-Ọjẹ onifuji nni, Wasiu Ọmọgbọlahan Adewale ti gbogbo aye mọ si Wasiu Ayinde, KWAM 1, lo n ba wi, wọn loun lo n kọrin bu, oun lo si pe ni agbaaya alainirori tori iwa to hu.

Nibi tọrọ naa ka Ọba Orin si ṣe n sọrọ naa lo leju koko bii ẹni ti inu n bi, bẹẹ lo n naka ikilọ leralera, ede Yoruba ilu oke lo fi sọrọ ọhun, o ni: “Awọn mọ, wọn mọ pe awọn lawa n ba wi, amọ wọn ọn nii dahun, wọn ọn nii ṣọrọ. Were mọ mutọ, kọ nii jana. To o ba i le ṣọrọ, wọn o maa bi ọ pe ṣe’wọ lo ṣọrọ, ọọ ṣọ pọ ọ ṣọ bẹẹ mọ”.

pọ awọn ti wọn mọ bo ṣe n lọ lagbo Fuji lasiko yii ni wọn ti n sọ pe Wasiu Ayinde, Oluaye Fuji, ti wọn tun n pe ni K1 de Ultimate ni onija Saheed Oṣupa to doju orin rẹ tuntun yii kọ. Wọn ni Wasiu lo huwa agbaaya pẹlu bo ṣe gba owo lọwọ Taye Currency, iyẹn Taye Akande Adebisi, lọjọ to n ba a sọrọ bi ija aarin oun ati ọga rẹ, Wasiu Alabi Ọdẹtọta ti gbogbo aye mọ si Wasiu Alabi Pasuma tabi Paso, ṣe maa pari. Wọn ni iwa ti Kwam1 ju ọhun bi Saheed Oṣupa nínú gidigidi, wọn ni iwa okanjuwa ni, o si ṣee ṣe ko jẹ eyi lo mu ki Oṣupa kọrin pe:

“Alabosi ẹda, onirikimọ,

O moju owo, o tun lahun lọlẹ,

Ko mu tọwọ ẹ wa, bọmọde fun un aa gbà,

Bikoko ile fun ùn ni burẹdi aa gba jẹ.”

Amọ awọn mi-in sọ pe ọrọ ija agba to tun bẹ silẹ lagbo Fuji yii ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, wọn ni ọrọ to ti wa nilẹ tipẹ ni, ati pe egbinrin ọtẹ lọrọ naa, ba a ṣe n pa ọkan ni omi-in n ru. Wọn ni ọrẹ imulẹ ni Saheed Oṣupa ati Pasuma latilẹwa, gbogbo yanpọnyanrin ati gbodo-n-ro’ṣọ to si ṣẹlẹ laaarin wọn lọdun diẹ sẹyin, eyi to mu ki ona ija fẹju kẹkẹ bii oju ogun tootọ ko ṣẹyin awọn to ko si wọn laaarin, wọn ni wọn kọ wọn síra wọn ni, ati pe ọga onifuji kan ni ọdada aarin wọn.

Sibẹ Taye Currency lawọn kan di ẹbi ọrọ yii ru, wọn loun ni eku ẹda to tun da gbogbo eleyii silẹ, wọn loun lo tigi bọ oju egbo ti ko tii jinna tan ti awuyewuye fi tun gb’ode, akọkọ latari ọrọ to kọkọ sọ nipa Pasuma eyi to da ija silẹ, ko too di pe Kolington Ayinla, Baba Alagbado ati Wasiu Ayinde n ba wọn pari rẹ. Ati pe iru owo ti Currency na fun Kwam 1 nile rẹ lọjọ to wọn ba a sọrọ ipẹtu saawọ ọhun, ko yẹ ko nawo bẹẹ, bi yoo ba si naa, ko yẹ ko ṣe fidio rẹ, ko si ju u sori afẹfẹ. Wọn lóhun tó ṣe yii ku diekaato, eyi lo sì tanna ran ibinu Saheed Oṣupa.

Sibẹ b’awọn kan lara awọn ololufẹ Saridon Papa, iyen Saheed Oṣupa, ṣe n gbosuba fún un, ti wọn n kan saara sí I pe akin ọmọ ti ki I gbagbakigba ni, bẹẹ lawọn mi-in n pariwo fun ùn pe ko jeburẹ lori ọrọ Oluaye Fuji, wọn ni ko ma ba Wasiu Ayinde ṣe fa-n-fa titi lọ, tori ọrọ le ṣe bii ere bíi ere di Isu ata yan-an-yan-an, bẹẹ òwe Yorùbá ni, ọrọ balẹ kan baale, bi ọrọ ba dagadangba tan, a maa kan jeejee ni mo jókòó mi.

Ẹ o ranti pe eyi ni orin àkànṣe keji ti Saheed Oṣupa yóò kọ lori lọgbọ-lọgbọ to n lọ Lagbo Fuji lasiko yii, latigba ti ọrọ Pasuma ati Currency to bẹrẹ. Bíi ose meji seyin lo ti kọkọ gbe orin kan jade ni’bi to ti loun mọ ohun ti ọpọ eeyan kọ mọ nidi iṣẹ Fuji, to si darukọ Pasuma, Obesere, oun funra ẹ, Oṣupa, ati Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister, o ni anọbi ni lawọn yẹn nidii ise Fújì, amo ko darukọ Wasiu Ayinde, Kollington Ayinla, at’awọn mi-in bẹẹ. Eyi lo ṣi n run nilẹ bii iso buruku, ko tii rún tan ti Jakky Oba Orin tun fi fibinu ju bombu ọrọ tuntun yii.

Ṣa o, Oṣupa ti leni toun n ba wi mọ ara ẹ, ko si to bẹẹ lati fesi. O jọ pe pe ọrọ ti n ba ọrọ bọ, eegun Alare!

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search