Itafaaji

Lẹyin iṣẹ abẹ jẹjẹrẹ ọmu, ẹ wo bi Tọpẹ Ọṣọba ṣe jijo ọpẹ lọsibitu

Owe Yoruba ni iku ti iba pa’ni, bo ba ṣi’ni ni fila, o t’ọpẹ, owe yii lo wọ ọrọ gbajumọ oṣere-binrin onitiata nni, Temitọpẹ Ọṣọba, ti ọrọ aisan lilagbara to ba a finra lati ọjọ pipẹ sẹyin, ati bo ṣe di ero ọsibitu, t’awọn oṣere ẹlẹgbẹ rẹ bẹrẹ sii ṣaajo rẹ lati doola ẹmi rẹ ṣi n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara titi dasiko yii, o jọ pe orukọ ti ro obinrin apọnbeporẹ naa, ọrọ rẹ t’ọpẹ, tori lẹyin iṣẹ abẹ aisan jẹjẹrẹ ọmu to ṣe, ara rẹ ti n ya, koda o ti n jijo ọpẹ n’ileewosan to wa bayii.

Ninu awọn fidio kan ti oṣere-binrin naa gbe sori ikanni ayelujara Instagiraamu rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2024, bo tilẹ jẹ pe ọsibitu ti wọn ti ṣiṣẹ abẹ fun un lo wa, ti gbogbo alẹmọ ati okun ti wọn so kọ ọ lara lasiko itọju rẹ ṣi wa lara rẹ, titi kan awọn bandeeji oriṣiiriṣii, sibẹ lẹgbẹ bẹẹdi rẹ ọhun, Tọpẹ Ọṣọba fi idunnu rẹ han pe Ọlọrun gbe iku ojiji fo lori oun, ijo lo fi dupẹ, bo ṣe n kọrin tidunnu-tidunnu, bẹẹ lo n tadireke, bii pe nnkan kan ko ṣe e rara.

Ṣaaju fidio to ti ki ijo mọlẹ, Tọpẹ kọkọ ṣafihan bi gbajugbaja oṣere-binrin ẹlẹgbẹ rẹ kan, Abilekọ Folukẹ Daramọla Salakọ, ṣe ṣabẹwo si i lọsibitu, o si sọrọ imoore nipa ẹ, o ni ki gbogbo awọn ololufẹ oun ba oun dupẹ lọwọ Folukẹ Daramọla gidigidi, tori niṣe lo duro ti oun bii iṣan ọrun ninu aarẹ yii, o na’wo na’ra, o tun dupẹ lọwọ gbogbo awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn dide iranlọwọ owo si oun. O lara oun ti n ya, oun ti lalaafia bayii.

Bo ṣe n sọ eyi naa ni Folukẹ naa n fesi pe inu oun dun pe aburo oun yii ti kọfẹ pada, o ni laipẹ Temitọpẹ yoo pada sidi iṣẹ rẹ pẹlu okun ati ilera to kọyọyọ, o lo maa lágbára gidi ni o.

Lati fidi eyi mulẹ, ninu fidio keji, orin ìyìn kan lede Gẹẹsi, eyi ti Moses Bliss ati Tim Godfrey gbe jade laipẹ yii lo gbe si i, ni Temitọpẹ ba ki ijo taa n wi yii mọlẹ, lo ba n kọrin pe:

“Evidence, evidence, full everywhere;

Testimony, testimony, dey everywhere;

Oh my God, na you do this one, evidence, testimony, full everywhere. Ati bẹẹ bẹẹ lọ

Ọpọ awọn oṣere tiata l’ọkunrin lobinrin at’awọn ololufẹ Temitọpẹ Ọṣọba ni wọn ti n ba a dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ajinde ara to jẹ́ fun un yii, ti wọn si n ki i kuu ewu.

Bidemi Kosọkọ ni: “Ọpẹ o, o ti bori ogun yii, Baby girl.”

Bimbọ Oshin ni: “Testimony nibi gbogbo ni loootọ o, lorukọ Jesu”.

Iyabo Ojo, toun naa ti lọọ kii Tọpẹ Ọṣọba lọsibitu to si fun un lẹbun owo nla kọ ọrọ tiẹ ṣoki, o ni: “Iwosan pipe lat’ọdọ Ọlọrun ni o.”

Mistura Asunramu ni: “Ki Ọlọrun bukun ẹ nigba gbogbo.”

Mo Bimpe naa fi ami ifẹ rẹpẹtẹ sibẹ lati fi idunnu rẹ han.

Tẹẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni awo ọrọ naa lu sita pe aisan gbẹmi-gbẹmi kan n ṣe arẹwa oṣere-binrin to jafara loko ere yii, bo tilẹ jẹ pe o ti pẹ to ti n ba kinni ọhun finra labẹnu, o si ti ṣe diẹ to ti lọ soko ere tabi kopa lawọn ibi ayẹyẹ gbogbo t’awọn ẹlẹgbẹ rẹ n lọ. Wọn lo wa lọsibitu, o ti n gba itọju.

Amọ ọrọ naa ya ọpọ awọn onitiata ẹlẹgbẹ rẹ lẹnu nigba ti Temitọpẹ funra rẹ sọrọ taanu-taanu ninu fidio kan to ṣe lori idubulẹ aisan to wa pe arun buruku, jẹjẹrẹ ọmu, t’awọn eleebo n pe ni breast cancer lo n ṣe oun, ati pe iṣẹ abẹ lọrọ kan bayii o. Iroyin agbọ-ṣe-haa lọrọ naa jẹ f’ọpọ eeyan.

Loju ẹsẹ lawọn ẹlẹyinju aanu ti dide iranwọ fun oṣere yii, bi wọn ṣe n seto ikowojọ, bẹẹ ni wọn n rọjo adua fun un pe kinni naa ko ni i m’ọna ẹmi rẹ.

Eyi ni inu wọn fi dun pe lẹyin iṣẹ abẹ naa, ara ọmọ Ọṣọba ti balẹ daadaa. Ireti sí wa pe yoo pada s’ẹnu iṣẹ rẹ ti yoo si maa da awọn ololufẹ rẹ lara yá lẹẹkan si i laipẹ jọjọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search